Mo lọọ ṣalaye fun Buhari pe mo fẹẹ dupo aarẹ Naijiria ni-Tinubu  

Faith Adebọla

Aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC to tun figba kan jẹ gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Sẹnetọ Bọla Ahmed Tinubu, ti sọ pe ohun to gbe oun de ileejọba ni Abuja ni lati fi erongba oun han fun Aarẹ Muhammadu Buhari pe oun feẹ dupo aarẹ ilẹ wa.

Lẹyin ipade bonkẹlẹ to ṣe pẹlu Buhari ni Mọnde, ọjọ Aje, ọsẹ yii, lo sọrọ naa fun awọn oniroyin nile ijọba niluu Abuja.

Ṣe ni aarọ kutu ọjọ Aje ni iroyin ti kọkọ gbe e pe ijiroro pataki kan n lọ lọwọ laarin Adari ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) yii ati Aarẹ Muhammadu Buhari nile ijọba apapọ to wa lolu-ilu wa, Abuja.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja, ni gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ ri naa, ṣabẹwo si Aarẹ Buhari, Oloye Bisi Akande si wa pẹlu wọn lọjọ naa.
Lọtẹ yii, Tinubu nikan ati Buhari ni wọn ṣepade, wọn si tilẹkun mọri ni, wọn ko faaye gba awọn oniroyin kankan.

Leave a Reply