Mo maa sin orileede yii pẹlu gbogbo ẹmi mi ti mo ba di aarẹ-Ọṣinbajo

Monisọla Saka
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni Igbakeji Aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo, ṣeleri nipinlẹ Taraba ati Yobe, pe ti wọn ba foun lanfaani lati tukọ orilẹ-ede yii, oun yoo sin in pẹlu gbogbo ọkan oun.

O ni awọn eeyan ilẹ Naijiria ko ni i kabaamọ pe wọn dibo yan oun gẹgẹ bii aarẹ wọn, nitori yoo pada ye wọn pe ẹni to kunju oṣuwọn ni wọn fiṣẹ ogun ran.
Ọṣinbajo sọrọ yii lasiko to ṣabẹwo sipinlẹ Taraba ati Adamawa, ni itẹsiwaju pẹlu ipade pẹlu awọn eekan ati aṣoju inu ẹgbẹ APC, lati le beere fun atilẹyin wọn fun ti idibo abẹle ẹgbẹ naa ti yoo waye nipari oṣu yii.
Ninu atẹjade kan ti Oludamọran agba fun Igbakeji Aarẹ lori eto iroyin, Laolu Akande, buwọ lu ti wọn pe akọle ẹ ni, ‘Ti wọn ba fun mi lanfaani lati dari orilẹ-ede yii, ma a sin in pẹlu gbogbo ọkan mi’.

O ni, “Idi ti mo fi fẹẹ di aarẹ ilẹ Naijiria ni lati sin awọn eeyan orilẹ-ede Naijiria, n ko ni idi mi-in ayafi ki n sin wọn.
“Mo mọ pe pẹlu ọdun meje ti mo lo nipo gẹgẹ bii Igbakeji Aarẹ, Ọlọrun ko fun mi ni iru anfaani bẹẹ pe ki n kan jokoo sibi kan ki n waa maa kọ itan iṣẹ ti mo ṣe gẹgẹ bii Igbakeji Aarẹ.
‘‘Gbogbo awọn iriri ti mo ni yii wa fun pe ki n le sin awọn eeyan ni, idi si niyi ti mo fi pinnu lọkan mi pe ti Ọlọrun ba fun mi ni anfaani lati sin awọn eeyan orileede yii, awọn eeyan ilẹ wa yoo ri i pe awọn ko ṣe aṣiṣe lati yan mi sipo nitori gbogbo okun, agbara ati otitọ ti mo ni ni ma a fi ṣiṣẹ’’ .
O fi kun un pe oun ko wa ipo naa lati fi ṣe ohunkohun, bi ko ṣe lati mu igbesi aye daa si i fun awọn eeyan orileede yii.
Nigba to n ba awọn aṣoju ipinlẹ mejeeji sọrọ, Ọṣinbajo fẹmi imoore han lori atilẹyin ti wọn ti n ṣe bọ latigba to ti kede erongba rẹ lati dupo aarẹ. O gba wọn niyanju, o ni o yẹ ki awọn eeyan naa mọ riri anfaani ti wọn ni lati ṣiṣẹ sin awọn araalu.
“Ara awọn nnkan pataki ti mo fẹẹ sọ fawọn aṣoju nibikibi ti mo ba lọ ni pe pataki ni ojuṣe awọn oloṣelu”. Ọlọrun ti fun wa lanfaani lati ṣiṣẹ sin awọn eeyan, iru anfaani yii lo si yẹ ka mọ riri rẹ, ka si maa yin Ọlọrun fun. Laarin ogunlọgọ awọn eeyan nilẹ yii, ẹyin tẹ ẹ wa nibi ni Ọlọrun ti yan lọna kan tabi omiiran, yala wọn yan yin sipo tabi wọn dibo yan yin sipo.
“Ipo yẹn ki i ṣe nitori ifẹ ara wa, bi ko ṣe lati sa ipa wa fun orilẹ-ede, ati lati m’aye rọrun fawọn eeyan wa. Anfaani nla gbaa ni lati sin awọn eeyan”.

Lamido ilu Adamawa, Muhammadu Mustapha, gba Ọṣinbajo lalejo laafin ẹ, nibẹ lo ti ran an leti pe orukọ oye tawọn fun un ni Jagaban ilẹ Adamawa.
Ori ade naa waa gbadura fun Ọṣinbajo pe yoo de ibi to n lọ pẹlu ogo Ọlọrun.
“Mo lero pe wiwa rẹ yoo mu imọlẹ wa si ilu Adamawa, nitori pe iwọ ni Jagaban ilu Adamawa. Mo gba a laduura pe wa a ṣaṣeyọri ninu ilakaka rẹ lati di aarẹ”.

Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Yobe, Ahmadu Fintiri, gbadura pe Ọlọrun yoo gba erongba ọkan Igbakeji Aarẹ, yoo si ṣaṣeyege.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Ṣeun to gun ale rẹ lọbẹ l’Ondo ni ṣe loun fi daabo bo ara oun

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ Ọmọbinrin ẹni ọdun mọkandinlogoji kan, Ṣeun Ṣọla ti ṣalaye idi to fi …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: