Mo mọ Tinubu daadaa, oun lo le ṣe aarẹ lọdun 2023- Alagba Faṣọranti

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

 

Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre to ṣẹṣẹ gbe kinni ọhun silẹ fun Oloye Ayọ Adebanjọ, Alagba Reuben Faṣọranti, ti sọ pe oun fara mọ ọn daadaa pe ki Aṣiwaju Bọla Tinubu, di aarẹ Naijiria lọdun 2023, nitori ẹni toun mọ daadaa ti yoo si ṣe ohun ti araalu n fẹ ni bo ba de ipo naa.

Ikọ to n polongo ibo fun Tinubu, eyi ti wọn n pe ni ‘South West Agenda For Asiwaju Bola Ahmed Tinubu’(SWAGA 23) lo ṣabẹwo sile Alagba Faṣọranti niluu Akurẹ, ti wọn waa beere fun atilẹyin baba naa.

Ninu ọrọ ti baba ẹni ọdun marundinlọgọrun-un(95) naa sọ fun wọn lo ti fi atilẹyin rẹ han fun Tinubu, baba naa sọ pe,’’Tinubu kunju oṣuwọn lati ṣakoso Naijiria, nitori oriṣiiriṣii nnkan lo ti gbe ṣe lorilẹ-ede yii. Mo fọwọ si i, mo si tun gba a ladura pe ki Ọlọrun jẹ ko ṣee ṣe fun un. Nitori to ba depo naa tan, gbogbo ohun ti a fẹ ni yoo ṣe. Tinubu ko ni i ja awọn ọmọ Naijiria kulẹ, mo mọ ọn daadaa’’

Baba fi kun un pe ọna kan ṣoṣo ti ipo aarẹ ko fi ni i bọ mọ Yoruba lọwọ lọdun 2023 ni ki gbogbo eeyan gbaruku ti Tinubu, o ni didun lọsan yoo so bi gbogbo ilu ba ṣatilẹyin fun un.

Ṣugbọn latigba ti baba ti sọrọ yii lawọn eeyan ti n bu ẹnu atẹ lu olori ẹgbẹ Afẹnifẹre tẹlẹ naa, oriṣiiriṣii ọrọ lo si n ja ran-in lori ayelujara bayii si baba naa, ti wọn n sọ pe ojo ogbo ti n da ọkunrin yii laamu, wọn ni ko daju pe o mọ ohun to n sọ.

Ọpọ eeyan lo n sọ pe ṣe baba ti gbagbe iku ọmọ rẹ tawọn Fulani pa lọdun 2019, Funkẹ Ọlakunrin, ni. Wọn ni ṣe ko ranti ọrọ ti Tinubu sọ nigba to lọọ ki baba naa nile lori iku Funkẹ, to ni ki i ṣe Fulani lo pa obinrin naa, abi maaluu wo lawọn to n sọ bẹẹ ri lọwọ awọn to pa Funkẹ.

Awọn mi-in tilẹ sọ pe afẹnifẹbi ni baba, o ti kuro ninu ẹgbẹ Afẹnifẹre. Bẹẹ lawọn mi-in sọ pe owo ti wọn gbe wa fun baba arugbo naa lo n ṣiṣẹ rẹ. Wọn ni nigba tawọn SWAGA 23 ko ti i wa sile rẹ, njẹ o polongo atilẹyin fun Tinubu bi, wọn ni owo ti wọn waa fi di Baba Faṣọranti lẹnu lo jẹ ko maa sọ ohun ti ko tọ sẹnu ẹni ti ọjọ ti dalẹ fun bii eyi.

Yatọ si Baba Faṣọranti, awọn ọba meji to tun fi atilẹyin wọn han fun Bọla Tinubu l’Ondo ni, Ọsẹmawe, Ọba Victor Kiladejọ, ati Abodi Ikalẹ, Ọba George Faduyile. Wọn ni ki gbogbo ọmọ Yoruba ti Jagaban lẹyin, nitori oun ni ipo aṣiwaju Naijiria tọ si.

Leave a Reply