Mo ti ṣetan lati gba isakoso ipinlẹ Ọṣun lọwọ Oyetọla – Lasun Yusuf

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Igbakeji olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin lorileede yii tẹlẹ, Ọnarebu Lasun Yusuf, ti fi ọwọ mejeeji sọya pe oun loun yoo di gomina ipinlẹ Ọṣun ninu idibo ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii.
Nigba to n sọrọ lẹyin ti wọn yan an gẹgẹ bii oludije funpo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party niluu Oṣogbo ni Lasun sọ pe oloṣelu to ba tun gbiyanju lati ṣeru ibo lorileede yii lẹyin ifẹhonu han EndSars, n wa wahala lasan ni.
Lori idi to fi lọ sinu ẹgbẹ oṣelu Labour Party lẹyin to kọwe fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ, Lasun, ẹni to ba Oyetọla du tikẹẹti ipo gomina loṣu Keji, ọdun yii, sọ pe gbogbo aye oun loun ti pinnu lati maa fi sin awọn araalu nitori oun ni imọlara nnkan ti wọn n la kọja.
O ke si awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati ṣiṣẹ takuntakun lori idibo gomina to n bọ yii, ati pe ti oun ba ti le ni ibo ọgọfa ni ile-idobo kọọkan, abuṣe ti buṣe.
Ọnarebu Lasun fi kun ọrọ rẹ pe ṣe ni gbogbo awọn ti wọn n sọ pe kikuro oun ninu ẹgbẹ APC ko nitumọ kan n tan ara wọn jẹ, nitori oun ti wa ninu oṣelu san-an-san-an lati ọdun 1989, to si jẹ pe oun ni oloṣelu ti ọrọ rẹ pẹ ju nile-ẹjọ to n gbọ ẹsun to ṣu yọ lẹyin idibo lorileede yii.

“Ti ẹ ba dibo fun mi lati di gomina, adinku yoo ba owo-ẹkọ, iṣẹ agbẹ yoo rọrun si i, eto-ilera yoo di eyi to wa larọọwọto gbogbo eeyan, awọn nnkan alumọọni tipinlẹ Ọṣun ni yoo si wa fun tolori-tẹlẹmu.

“Inu mi dun pe ẹgbẹ Labour Party fun mi lanfaani lati dupo gomina labẹ asia wọn, mo si mọ ọn loore. Mo waa fẹ ki gbogbo yin pada lọ si ile idibo yin lati lọọ ṣiṣẹ, nitori ojubọrọ kọ la fi maa n gba ọmọ lọwọ ekurọ.
“Ohun ti mo nilo ni ibo ọgọrun-un si ọgọfa ni ile idibo kọọkan to wa kaakiri ipinlẹ Ọṣun, ti mo ba ti ri i, mo ti di gomina. Ile idibo ẹgbẹrun mẹta o le mẹwaa lo wa nipinlẹ Ọṣun.
“Mo ni idaniloju pe mo maa wọle nitori gbogbo nnkan amuyẹ ni mo ni. Mo mọ iru awọn ti mo fẹẹ koju, ṣugbọn oloṣelu to ba tun n gbero lati yi ibo lẹyin nnkan ti a ri lasiko EndSars n fori ọka họmu ni, oko iparun lo si n lọ”

Leave a Reply