Mọto ayọkẹle mẹwaa ati tirela kan jona deeru ninu ọgba ajọ LASTMA l’Oshodi

Faith Adebọla

Ina nla kan ti ṣọṣẹ lagbala ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ loju popo nipinlẹ Eko LASTMA, ninu ọgba wọn to wa ni ile LSTC, ọna marosẹ Oṣodi si Apapa, l’Oshodi.  Ọkọ mọkanla ni ina naa bajẹ kanlẹ ki wọn too le kapa rẹ nirọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.

Nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ naa niṣẹlẹ ọhun waye nigba ti ina ṣadeede ṣẹ yọ laarin awọn ọkọ ti wọn fofin gba lọwọ awọn ọlọkọ to lufin irinna, ti wọn ko si ti i waa gba ọkọ wọn.

Titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, ko ti i sẹni to mọ pato ohun to ṣokufa ina naa, a ko gbọ pe ẹnikẹni ba iṣẹlẹ naa rin, bẹẹ ni ko sẹni to farapa, ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si ọrọ pajawari nipinlẹ Eko, LASEMA, ati tileeṣẹ panapana, titi kan awọn agbofinro fi n ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe ina naa ku patapata.

Nigba ti Alukoro ajọ LASEMA, Ọgbẹni Nosa Okunbor, n sọrọ nipa ijamba naa, o ni ọkọ ayọkẹlẹ mẹwaa ati tirela kan nina naa jo deeru.

One thought on “Mọto ayọkẹle mẹwaa ati tirela kan jona deeru ninu ọgba ajọ LASTMA l’Oshodi

  1. Ero mi ni wipe ki awon to ni oko tabi tirela yii gba moto won pada ni tuntun. Yoruba bo wo ni ile oba to jo, ewa lo bu si. Awon ti gbanba yii selesi ki won ri wipe wo gba oko pada lowo ijoba eko ati ajo Lasma.
    Olorun lo da ejo fun won, ero awon alaise lo se ejo gbigbona fun won . Awon olori buruku am robber people.

Leave a Reply