Mọto lọọ ya ba iya atawọn ọmọ rẹ meji l’Ogbomọṣọ, lo ba te wọn pa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Igbe ikunlẹ abiamọ lawọn olugbe atawọn  abanikẹdun n ke lagbegbe Crown FC Hostel, niluu Ogbomoṣọ, nibi ti ijamba ọkọ ti gbẹmi eeyan mẹta, ti ọpọ eeyan si fara pa yannayanna.

Laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, niṣẹlẹ ọhun waye nitosi ilegbee ẹgbẹ agbabọọlu Crown FC, iyẹn Crown FC Hostel, to wa lọna Ọja Tuntun, niluu Ogbomọṣọ.

Ohun to tubọ mu ki isẹlẹ yii pa gbogbo abiamọ agbegbe naa lẹkun ni pe ẹjẹ kan naa lawọn mẹtẹẹta to ku ọhun, iya atọmọ rẹ meji ni.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ijanu ọkọ ayọkẹlẹ Mistubishi ọhun ti nọmba ẹ jẹ LND 69 AR lo feeli lojiji, eyi to mu ki ọkọ naa ya bara kuro loju titi, to lọọ kọ lu iya kan ti ọpọ eeyan mọ si Iya Onike pẹlu awọn ọmọ rẹ meji ninu ṣọọbu wọn nibẹ.

Olugbe adugbo ọhun kan to fiṣẹlẹ yii to akọroyin wa leti sọ pe awọn to wa nitosi lasiko iṣẹlẹ to ba ni ninu jẹ yii ni wọn sare gbe iya atawọn ọmọ rẹ mejeeji naa lọ sileewosan fun itọju.

Ṣugbọn awọn dokita ko ri ipa kankan ṣa lati ra ẹmi wọn pada lọwọ iku oro, o jọ pe loju-ẹsẹ ni gbogbo wọn ti jade laye.

Wọn ni ileewosan lọpọ ninu awọn to fara pa ninu iṣẹlẹ yii ṣi wa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Ninu awọn to fara pa ọhun la ti ri dẹrẹba mọto to lasidẹnti naa pẹlu ero meji to wa ninu ẹ.

 

Leave a Reply