Faith Adebọla, Eko
Ikọ tuntun tijọba Eko ṣẹṣẹ ṣefilọlẹ rẹ lati gbogun ti awọn onimọto to ba gba ọna ọlọna, (one-way), ti sọ ọ di mimọ pe laarin ọjọ kan ṣoṣo, mọto mẹrinlelogoji lawọn mu kaakiri ipinlẹ Eko, awọn ọkọ naa si ti wa lakolo ọlọpaa.
Asaaju ikọ naa, Ọgbẹni Ṣọla Jẹjẹloye, to tun jẹ Kọmanda fawọn ọlọpaa to n kọwọọrin pẹlu gomina ipinlẹ Eko sọrọ yii lọjọ Abamẹta pe lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, lawọn mu awọn alaigbọran onimọto naa, tawọn si gba awọn ọkọ ti wọn wa ta ko ofin irinna naa nidii wọn loju ẹsẹ.
O ṣalaye pe awọn ọlọpaa meji lawọn ba ninu mọto pikọọbu kan ti wọn kọ “Escort” sara ẹ, mọto naa dori kọ ọna Oṣodi si Apapa, ṣugbọn ọna awọn ọlọkọ to n bọ lati Apapa si Ọsodi lo gba, o waa tan ina iwaju mọto rẹ silẹ bii pe alẹ lo wa, tori kawọn ọkọ baa le ya fun un. Agbegbe ibudokọ Toyota ni wọn ti mu un.
O lawọn tun mu ọkọ ayọkẹlẹ kan ti ọmọ ogun ori-omi (Navy) kan wa, Iyana Itirẹ, lọna Apapa, ni wọn ti mu oun ni tiẹ, wọn si gba ọkọ ayọkẹlẹ naa nidii ẹ.
Ọpọ awọn onimọto mi-in ti wọn mu, yatọ sawọn to gba ọna to ta ko ofin irinna, jẹ nitori wọn gba ọna akanṣe to wa fawọn bọọsi BRT, tabi ki wọn maa ṣediwọ fun lilọ geere ọkọ loju popo. O lawọn tun mu awọn ọlọkada meloo kan tawọn naa ṣẹ sofin yii.
Jẹjẹloye ni awọn ọlọkọ kan tiẹ gbiyanju lati fori sọ mọto tawọn ikọ naa fi n ṣiṣẹ, nibi ti wọn ti n sare asapajude ki wọn le raaye sa lọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aje, Mọnde to kọja yii, nijọba ṣagbekalẹ ikọ agbofinro tuntun ti wọn ko niṣẹ meji ju mimu awọn onimọto to ba gba wan-n-wee lọ.
Pẹlu eyi, o ni ojoojumọ lawọn oṣiṣẹ oun yoo maa jade lati gbogun ti awọn ọnimọto ti wọn n rufin gbigba ọna ọlọna yii, tori iṣoro yii ti di wahala nla kan nipinlẹ Eko, o si ti fẹẹ mọ awọn eeyan kan lara lati maa fi gosiloo kẹwọ ṣe ohun to lodi sofin.