Mọto sọ ijanu rẹ nu, lo ba ṣeku pa tẹgbọn-taburo ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Owurọ kutukutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni ọmọ ẹgbọn, ọmọ aburo, Sikiru Olola ati Jamiu Olola kagbako iku ojiji, nigba ti ọkọ ayọkẹlẹ kan kọ lu ọkada wọn ni ilu Elemere, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe iṣẹ awọn to n ṣiṣẹ ẹrọ omi (plumbing) lawọn ọmọ tẹgbọn-taburo yii yan laayo, ati pe lara awọn eroja ti wọn fẹẹ fi ṣiṣẹ ti wọn ra ti ko dara ni wọn fẹẹ lọọ da pada si ibi ti wọn ti ra a niluu Ilọrin. Nigba ti wọn de odo Busa to wa ni opopona Malete si Ilọrin, ni ọkọ ayọkẹlẹ alawọ funfun kan padanu ijanu rẹ, to lọọ ya ba wọn, to si tẹ awọn mejeeji pa.

Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ to ba akọroyin wa sọrọ sọ pe oun ni ẹni akọkọ to ṣe kongẹ iṣẹlẹ ọhun. O tẹsiwaju pe oun fẹẹ ran wọn lọwọ, ṣugbọn nigba ti oun ri i pe ọkan ti ku ninu wọn loun ba ẹsẹ oun sọrọ nitori oun ko fẹẹ ko si wahala awọn agbofinro.

Agọ ọlọpaa to wa ni ilu Sao, ti yọju sibi iṣẹlẹ naa, wọn si mu akẹkọọ Fasiti Kwasu, to wa ọkọ to ṣeku pa awọn ọkunrin mejeeji yii fun iwadii to peye.

Titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, ṣe ni gbogbo ilu Elemere kan gogo. Ileesẹ ọlọpaa si sọ pe dandan ni kawọn ṣe iwadii lori iṣẹlẹ naa.

 

Leave a Reply