Mọto ya pa iya onibọọli lẹgbẹẹ titi l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla

 

Iya kan to n ta bọọli ati iṣu sisun lẹgbẹẹ titi lagbegbe Ogo-Oluwa, loju-ọna Gbọngan si Oṣogbo, la gbọ pe mọto kan ya pa lọsan-an ọjọ Iṣẹ́gun, Tusidee, ọsẹ yii.

Ibi ti iya naa jokoo si to ti n sun bọọli ati iṣu ni mọto Honda alawọ ewe to ni nọmba GGE 235 GL naa ti lọọ ya ba a, ti iya naa si ku loju-ẹsẹ.

A gbọ pe ko pẹ rara ti iya naa debẹ, to si bẹrẹ ọja rẹ ni tita tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, ọmọkunrin to wa mọto ọhun naa si fara pa pupọ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ajọ ẹṣọ ojupopo l’Ọṣun, Agnes Ogungbemi, ṣalaye pe ere asapajude ti onimọto ọhun sa lo ṣokunfa ijamba mọto naa.

Ogungbemi fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti gbe awọn mejeeji lọ sileewosan, bẹẹ ni wọn ti wọ mọto naa lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Ataọja.

 

Leave a Reply