Musa fi ileeṣẹ ọlọpaa lu Halimọt ni jibiti owo nla l’Agọ-Iwoye

Gbenga Amos, Ogun

Akolo awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni ọkunrin to tẹsẹ bọ pampẹ ofin yii, Alaaji Musa Araokanmi, wa bayii latari bi baba agba naa ṣe purọ pe oun wa lara awọn araalu to ba ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣiṣẹ, oun si n ba wọn mojuto awọn ọkọ tileeṣẹ ọlọpaa fẹẹ ta, lo ba lu obinrin oniṣowo kan, Halimọt Ọlọrunlomẹru, ni jibiti. Miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna irinwo Naira (1.4 million) lo gba lọwọ ẹ p’oun maa fi ba a ra ọkọ ati ọkada, ṣugbọn alọ lo ri, ko ri abọ.

Halimọt lo lọọ fẹjọ sun ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Agọ-Iwoye, pe ki wọn gba oun, latinu oṣu Kẹfa, ọdun 2023, ni Alaaji yii ti gba owo lọwọ oun, to loun maa fi ba oun ra ọkọ ayọkẹlẹ ati ọkada meji, awọn si jọ dunaa-dura lori ẹ, o ni koun lọọ san owo naa sinu akaunti rẹ, ati pe laarin ọjọ diẹ, ọja toun fẹẹ ra naa maa jade.

O nidii toun fi fọkan tan afurasi naa, toun si fi ko owo fun un ni pe o pera ẹ ni ọmọ igbimọ PCRC, (Police Community Relations Committee), iyẹn igbimọ to n ṣoju araalu lọdọ awọn ọlọpaa, ati pe ileeṣẹ ọlọpaa Ogun fẹẹ ta awọn ọkọ ati ọkada to wa lakata wọn ni gbanjo, oun si ni wọn fi ṣe alamoojuto kinni naa, oun o mọ pe ‘gbaju-ẹ’ lo fẹẹ ṣe foun.

O ni atigba towo ti bọ si i lọwọ tan lo ti n foni-doni-in, fọla-dọla foun, pẹlu oriṣiiriṣii awawi, igba to si ya lo di pe oun ko ri i mọ, oun beere ẹ, wọn ni ko dagbere fẹnikan to fi poora bii iso.

Latigba ti Halimọt ti fẹjọ sun yii ni wọn ti n wa Alaaji Araokanmi, ko sẹni to gburoo ẹ rara fun bii ọdun meji, afi bẹnikan ṣe kẹẹfin ẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ to pari yii, ni wọn ba ta Halimọt lolobo, kia loun naa si ti kan sawọn ọlọpaa, n ni DPO Agọ-Iwoye, SP Noah Adekanye, ba paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ lati lọọ mu un.

Lagọọ ọlọpaa, Araokanmi ni ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ, o loootọ loun gba owo naa, ati pe irọ loun pa boun ṣe sọ pe ọmọ igbimọ CPRC loun, oun o si ṣe alamoojuto ọkọ tita kankan fawọn ọlọpaa.
Wọn beere ibi ti owo to gba naa wa, ṣugbọn ko fesi pato kan, niṣe lo n tẹwọ.

Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ kawọn ọtẹlẹmuyẹ tubọ tuṣu desalẹ ikoko lori ọrọ yii. O ni laipẹ, awọn maa foju afurasi onijibiti naa bale-ẹjọ.

Leave a Reply