Ọga ọlopaa patapata, Muhammed Adam, ti yan Ọmọọba Muyiwa Adejobi gẹgẹ bii agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko. Eyi ni pe gbogbo ohun to ba ṣẹlẹ lọdọ awọn ọlọpaa, tabi laarin awọn araalu pẹlu ọlọpaa, lẹnu Adejọbi lẹ o ti gbọ ọ.
Adejọbi ki i ṣe ọgbẹri nidii ise igbẹnusọ yii, nitori iṣẹ to n ṣe fawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun lati ọdun 2008 titi di 2016 ni. Kọmiṣanna ọlọpaa to pada di igbakeji ọga agba pata, Abdul Majid Ali, lo mu un kuro ni ipinlẹ Ogun nigba ti wọn gbe oun ga, to si mu un lọ si ilu Eko ni Zone 2. Nibi yii naa lo ti ṣiṣẹ fun ọpọ igba, ko too tun tẹ le ọga yii lọ si Abuja nigba ti wọn gbe e lọ sọhun-un. Igbakeji ọga ọlọpaa patapata yii, Ali, naa lo ba ṣiṣẹ titi ti tọhun fi fẹyin ti, ko too wa di pe wọn ni ki Adejọbi maa bọ lEkoo ko wa ṣe agbẹnusọ wọn.
Ọmọọba Adejọbi kawe ni yunfasiti Ibadan, o si gba oye nibẹ, bẹẹ lo kawe lAmerika, to tun lọ si awọn idanilekọọ loriṣiriṣi, toun naa si di ọkan ninu awọn ọga nidii iṣẹ naa. Ọmọọba ilu Owu ti ipinlẹ Ọṣun ni, ọpọlọpọ ilu lo si ti ṣiṣẹ kari Naijiria. O daju pe iriri nla lo n gbe bọ lEkoo yii, tori iṣẹ to mọ ọn ṣe lo n bọ waa ṣe.