Lasiko tawọn ọlọpaa n le awọn oluwọde, ti wọn n da omi gbigbona si wọn laaa, ti wọn si n yinbọ soke gbau gbau lati fi tu wọn ka ni ibọn ti lọọ ba ọmọbinrin kan ti ko ju ọdun mẹrinla lọ ni ṣọọbu obi rẹ to ti n patẹ miniraasi ti ya rẹ n ta.
Niṣe ni awọn eeyan bẹrẹ si i sunkun, ti wọn si n ṣepe fun awọn agbofinro fun iku ọmọ naa.