Nibi tawọn eleyii ti n ṣiṣẹ ajagungbalẹ lọlọpaa ti ko wọn l’Ado-Odo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ajagungbalẹ lawọn ọlọpaa pe awọn ọkunrin mẹrin yii, Najimu Ojumọla, Monday Ọlalẹyẹ, Kẹhinde Martins ati Felix John. Ọjọruu, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu karun-un yii, ni wọn mu wọn lasiko ti wọn n fa rogodiyan nitori ilẹ labule Babaọdẹ-onibuku, l’Ado-Odo Ọta.

Teṣan ọlọpaa Onipaanu ni wọn ti gba ipe pe awọn kan ti gba Abule Babaọdẹ-onibuku kan, wọn ko nnkan ija oloro rẹpẹtẹ wa, wọn ko si jẹ kawọn ara abule lọ sibi kan.

CSP Bamidele Job, DPO teṣan naa atawọn ikọ rẹ gba abule ọhun lọ, nibẹ ni wọn ti ba awọn ajagungbalẹ naa ti wọn n pitu ọwọ wọn.

Niṣe ni wọn si tiẹ kọju ija sawọn ọlọpaa naa, wọn si ti ṣe ọlọpaa meji, ASP Tajudeen Adeleke ati Inspẹkitọ Babatunde Ọlayiwọla leṣe. Ṣugbọn awọn agbofinro pada kapa wọn, wọn si ri Najimu Ojumọla ati Monday Ọlalẹyẹ mu.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ṣalaye pe nigba ti awọn ọlọpaa n gbe awọn ajagungbalẹ meji yii lọ, niṣe lawọn eeyan wọn yooku lọọ dena de wọn n’Idiroko, wọn si fẹẹ fipa gba awọn meji ti wọn mu naa silẹ. Ṣugbọn ọwọ awọn agbofinro ju tiwọn lọ, nigba naa ni wọn si ri Felix John ati Kẹhinde Martins mu.

Ọta ibọn mẹjọ ti wọn ti yin, ọta ibọn ẹyọ kan ti wọn ko ti i yin,  ada kan, ọkada Bajaj mẹta ati mọto ayọkẹlẹ Toyota Corolla kan ti nọmba ẹ jẹ FST 42 FT ni wọn ri gba lọwọ wọn.

Wọn ti ko wọn lọ sẹka iwadii iwa ọdaran nipinlẹ Ogun, bẹẹ ni wọn kilọ fawọn ajagungbalẹ yooku pe ki wọn ko ara wọn kuro nipinlẹ yii, nitori ipinlẹ Ogun ki i ṣe ibuba wọn.

Leave a Reply