Saraki, Ahmed atawọn mi-in to ja Kwara lole gbọdọ foju bale-ẹjọ- Buhari

Stephen Ajagbe, Ilorin

Alaga igbimọ tijọba gbe kalẹ lati tana wadii bi awọn gomina meji ana ni Kwara; Abubakar Bukọla Saraki ati Abdulfatah Ahmed ṣe ta dukia ijọba laarin ọdun 1999 si 2019, Amọfin Hussein Buhari, ti ni awọn mejeeji pẹlu awọn mi-in to lọwọ ninu jija ipinlẹ naa lole gbọdọ foju bale-ẹjọ.

Buhari sọrọ ọhun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nigba tigbimọ naa gbe abajade iwadii wọn kalẹ fun Gomina Abdulrahman Abdulrazaq.

O ni o yẹ kijọba gba awọn dukia kan ti wọn lu ni gbanjo lowo pọọku fawọn ọrẹ wọn pada, ki wọn si ṣẹwọn bi ile-ẹjọ ba ri i pe wọn jẹbi ẹsun jibiti.

O ni ohun iyalẹnu lo jẹ fun igbimọ naa nigba ti wọn tuṣu desalẹ ikoko nipa bawọn to ṣejọba lọ ṣe sọ dukia Kwara di omi odo, ti wọn si n gbọn ọn fun anfaani ara wọn.

O fikun un pe awọn ranṣẹ pe awọn tọrọ naa kan lati waa ṣalaye tẹnu wọn, ki wọn si wẹ ara wọn mọ ninu ẹsun ti wọn fi kan wọn, ṣugbọn ko si ọkankan ninu wọn to yọju.

Buhari ṣalaye siwaju pe ọpọlọpọ iwa ibajẹ ati ijẹkujẹ lawọn eeyan ọhun lọwọ si lori idasilẹ oko Shonga Farms, Satellite Motel, ati tita awọn dukia ijọba to wa nipinlẹ Kaduna, Abuja ati ilu Eko.

O gba gomina niyanju lati ṣe ọkan akin, ko si mu aba tigbimọ naa gbe kalẹ ṣẹ, nipa bẹẹ, gbogbo awọn ti aje iwa ibajẹ naa ṣi mọ lori ki wọn foju wina ofin.

“Ofin to de eto idibo ti ni ẹnikẹni to ba jẹbi iwa ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu ko gbọdọ dipo oṣelu mu fun ọdun mẹwaa gbako. Idunnu wa ni pe gomina yoo tẹle awọn aba ta a ṣe, yoo si gbe igbimọ ti yoo mu aba naa ṣẹ kalẹ ni kiakia.”

Nigba to n sọrọ lori awọn iwa jibiti tawọn to ṣejọba ṣaaju ṣe, o ni fun apẹẹrẹ, ilẹ tijọba iṣaaju ti ya sọtọ fun kikọ ile-ẹjọ giga to wa lagbegbe Tankẹ, awọn Bukọla ati Ahmed pin ilẹ naa mọ ara wọn lọwọ, wọn si fi kọ otẹẹli, ile ounjẹ igbalode ati bẹẹ lọ.

“Ijọba ni lati wọ wọn lọ sile-ẹjọ, ti wọn ba jẹbi, ki wọn jẹ iya to ba tọ si wọn. Awọn oṣiṣẹ ijọba to ba wọn lọwọ ninu iwa jibiti naa gbọdọ foju bale-ẹjọ.

O ke si ijọba lati wo otẹẹli Noktel palẹ, nitori pe ori ẹrọ to n pese omi si Agba Dam ni wọn kọ ọ le, ko si jẹ ki omi le de ibi to yẹ ko de. Bakan naa, gbogbo ilẹ ileeṣẹ amohun-maworan KWTV lawọn to ṣejọba naa ta tan, lai bikita nipa ofin to ni ile gbọdọ jinna diẹ si ẹrọ alatagba tileeṣẹ to n gbohun safẹfẹ n lo. O ni iyalẹnu lo jẹ fawọn nigba tawọn ri gbogbo nnkan wọnyi.

 

Leave a Reply