Monisọla Saka
Ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan bayii ni tolohun lọrọ da fun awọn ọmọkunrin meji kan, Victor Stephen, ẹni ọdun mẹtalelogun(23) ati Sunday Michael, toun jẹ ẹni ogun ọdun (20), ti wọn kundun ki wọn maa ja awọn eeyan lole lori biriiji abi ti wọn ba n fẹsẹ rin lọ kaakiri awọn adugbo niluu Eko.
Awọn afurasi meji ọhun ko sọwọ ikọ ọlọpaa ayaraṣaṣa RRS, ẹka ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kejila, ọdun yii.
ALAROYE gbọ pe ogbologboo ni awọn ọmọkunrin mejeeji yii ninu ki wọn maa dena de awọn eeyan to n gba ori biriiji ẹlẹsẹ to wa lagbegbe Alausa si Ketu, to wa lopoopona marosẹ Eko si Ibadan, ti wọn yoo si gba gbogbo ohun ti wọn ba ri lọwọ iru ẹni bẹẹ.
Iru rẹ naa ni wọn ṣe lọjọ Ẹti yii. Ilẹ ko ti i mọ tan lasiko ti wọn n le ẹni ti wọn fẹẹ ja nnkan gba lọwọ ẹ lọ, ti tọhun si fere ge e. Bẹẹ lawọn naa gba tẹle e, ti wọn si n wa ọna lati gba a mu, asiko naa ni wọn ko sọwọ awọn ọlọpaa RRS.
Ninu atẹjade ti ẹka ileeṣẹ ọlọpaa RRS fi lede ni wọn ti sọ pe, “Ni deede aago marun-un aarọ kutukutu ọjọ Jimọ, ọjọ kẹsan-an, oṣu yii, lawọn afurasi meji kan, Victor Stephen, ẹni ọdun mẹtalelogun(23) ati Sunday Michael to jẹ ẹni ogun ọdun (20), ko si panpẹ awọn oṣiṣẹ RRS lori biriiji ẹlẹsẹ agbegbe Ketu si Alausa, loju ọna marosẹ Eko si Ibadan.
Niṣe lawọn mejeeji lugọ lati dena de awọn to ba n ji jade, ti wọn yoo si ja iru ẹni bẹẹ lole tabi ki wọn tun lu u nilukulu mọ ọn to ba ba wọn ṣe agidi.
‘‘Ẹni kan to n gba ori biriiji naa kọja lati sọda sodikeji laaarọ kutukutu ni wọn n le lọ ti wọn fi ko sọwọ awọn ọlọpaa ti wọn paaki ọkada kalẹ sori biriiji lati maa mojuto ohun to n lọ layiika.
‘‘Wọn ti ko awọn afurasi yii lọ si teṣan fun ifọrọwanilẹnuwo ati iwadii.