O ya mi lẹnu pe APC le fa Musulumi meji kalẹ funpo aarẹ ati igbakeji-Jonathan

Faith Adebọla

 Iṣin wo o, ikoro wo o, ọhun a ba jọ wo, gigun ni i gun, olori orileede wa ana, Ọmọwe Goodluck Jonathan, ti fi erongba rẹ han lori awuyewuye to n lọ lagbo oṣelu nipa ki aarẹ orileede ati igbakeji rẹ jẹ ẹlẹsin kan naa, Jonathan ni oun ko fara mọ ọn, oun ko si fọwọ si i rara, o ni aṣa ti ko daa fun eto iṣejọba wa ni, ati pe ewu gidi ni tiru nnkan bẹẹ ba ṣẹlẹ.

Jonathan ni yatọ si pe aṣa naa ko yatọ si iwa anikanjọpọn ẹsin, tori ki i ṣe ẹsin kan ṣoṣo lo wa ni Naijiria, o ni ewu lo maa jẹ ti ẹlẹsin Musulumi meji ba jẹ aarẹ ati igbakeji, tabi ti ẹlẹsin Kirisitẹni meji ba jẹ aarẹ ati igbakeji. O ni ta lo maa maa ṣakoso orileede nigba tawọn mejeeji ba lọ si mẹka lọọ jọsin, abi nigba ti wọn ba lọọ kirun Jimọ ọsọọsẹ, ko ṣaa gbọdọ si alafo ninu iṣejọba?

Nibi ayẹyẹ ikojade iwe kan ti wọn fi sọ itan ati iriri adari ẹsin tẹlẹri ni ṣọọṣi to wa nileeṣẹ Aarẹ, Ẹni-Ọwọ Onwuzurumba Obiama, eyi to waye niluu Abuja, laarin ọsẹ yii mni Jonathan ti sọrọ yii.

Jonathan ni: “Nigba ti mo wa nipo igbakeji aarẹ Naijiria, aṣa to wa nilẹ ni pe ti Musulumi ba ti jẹ aarẹ, igbakeji ẹ gbọdọ jẹ Kirisitẹni, bo ba si jẹ Kirisitẹni l’aarẹ, Musulumi ni yoo ṣegbakeji ẹ. Ni Naijiria, ọpọ ajọdun ati ayẹyẹ ẹsin lo wa, bẹẹ naa lawọn ajọdun to jẹ ti orileede wa bii ajọdun ominira, nibi tawọn Musulumi ati Kirisitẹni ti maa ṣadura forileede wa.

Tori ọwọ pataki lawọn ọmọ orileede yii fi mu ọrọ ẹsin, o kọ mi lominu gidi nigba ti mo gbọ pe aarẹ ati igbakeji ẹlẹsin kan naa lawọn kan fa kalẹ. Loootọ, lawọn ipinlẹ, iru ẹ le waye, ṣugbọn ni ti ijọba apapọ, ta lo fẹẹ ṣoju fawọn ẹlẹsin keji yii lasiko ayẹyẹ tabi nigba ti aarẹ ati igbakeji ẹ ba lọ sibi eto ẹsin wọn?”

Aarẹ tẹlẹri naa beere bẹẹ, o si sọ pe oun ko fara mọ iru iyansipo ẹlẹsin kan naa ọhun.

Tẹ o ba gbagbe, titi dasiko yii ni awuyewuye ṣi n lọ lori ọrọ yii, paapaa lori ẹrọ ayelujara, ọpọ araalu lo si ti fi aidunnu wọn han si yiyan oludije ẹlẹsin kan naa sipo aarẹ ati igbakeji, eyi to mu kawọn kan kọyin si ẹgbẹ oṣelu APC.

Leave a Reply