Nibi tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ti n ṣe ayẹyẹ ọjọọbi lawọn ọlọpaa ti ko wọn l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ẹka ileeṣẹ iwadii lawọn afurasi ọdaran mọkandinlogun tọwọ awọn agbofinro ba l’Ọjọruu, Tọsidee, ọsẹ yii wa bayii. Ẹsun ṣiṣe ẹgbẹ okunkun tijọba ka leewọ ni wọn fi kan wọn, wọn ni nibi ti wọn ti dana ariya ni wọn ti lọọ fi pampẹ ofin gbe wọn.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ikọ amuṣẹya kan (Strike Team) ti kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, ṣẹṣẹ da silẹ lati mojuto ọrọ awọn ẹlẹgbẹ okunkun l’Ekoo lo ṣiṣẹ naa, awọn ni wọn kẹẹfin mejila lara wọn ni otẹẹli Celina, to wa lagbegbe Bariga, nipinlẹ Eko, wọn lawọn n ṣe ayẹyẹ baidee fun ọkan lara wọn.

Nigba ti wọn yẹ ara wọn wo, wọn ri awọn nnkan idanimọ ẹgbẹ okunkun, fila ati aṣọ dudu ti wọn ya aworan ẹgbẹ wọn si, wọn si tun ka ọpọ egboogi oloro bii igbo, kokeeni, atawọn nnkan ija mi-in mọ wọn lọwọ.

Bi wọn ṣe mu wọn lo jẹ ki wọn gbọ nipa awọn ibuba kan ti wọn jẹwọ pe awọn ẹlẹgbẹ okunkun mi-in wa lagbegbe Ṣomolu, kia lawọn ọlọpaa tẹkọ leti lọ sibẹ, wọn si ri awọn meje mi-in ṣa kaakiri ibi ti wọn sa pamọ si.

Kọmiṣanna ọlọpaa ti ni ki wọn ko gbogbo wọn lọ si ẹka ikọ Strike Team, fun iwadii, ki wọn si le foju bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply