Nibi tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ti n daro ẹlẹgbẹ wọn to ku lawọn ọlọpaa ti mu wọn l’Ogijo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bi awo ba ku, awo aa ṣedaro awo, lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹjọ kan fi ọrọ wọn ṣe l’Ogijo, nipinlẹ Ogun, lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹsan-an yii, nigba ti wọn lori-laya, ti wọn gbe akọle ẹgbẹ Eiyẹ ti wọn wa dani nita gbangba, ti wọn ya fọto ẹni to ku naa si i pẹlu, ti wọn si n wọde kiri pẹlu jagidijagan.

O kan jẹ pe kinni ọhun ko so eeso rere fun wọn ni, nitori nibi ti wọn ti n wọde naa ni olobo ti ta awọn ọlọpaa, bi wọn ṣe waa ko wọn niyẹn.

Yatọ si pe o lodi sofin lati ṣafihan ara ẹni bii ọmọ ẹgbẹ okunkun, ọmọ ọlọmọ to n lọ jẹẹjẹ rẹ, Onome Iduru, ọmọ ọdun mẹrindinlogun, tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii yinbọn lu nikun, tun jẹ ẹsun mi-in tawọn ọlọpaa fi mu wọn lọjọ yii.

Awọn mẹjọ naa, gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fi iṣẹlẹ naa to ALAROYE leti ṣe darukọ wọn ni: Ọlatunji Ọpẹyẹmi; ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ( 26), Ayuba Oduọla; ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25),  Ṣobọwale Abiọdun; ẹni ọdun mejidinlọgbọn ( 28), Ṣobọwale Sunday; ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ( 25), Adelọwọ Ọlalekan; ẹni ọdun mejilelọgbọn (32), Kareem Lanre; ẹni ọdun mọkanlelogun ( 21)’ Emmanuel Adebisi; ẹni ọdun mọkanlelogun (21) ati Tobilọba Wasiu toun  jẹ ẹni ogun ọdun.

Ki i ṣe pẹlu irọrun lawọn ọlọpaa mu wọn, gẹgẹ bi Alukoro ṣe ṣalaye. Awọn ọmọ Ẹiyẹ naa ba awọn ọlọpaa mu nnkan nilẹ ki apa awọn agbofinro too ka wọn.

Nigba tọwọ ba wọn tan, awọn ọlọpaa gba kinni ti wọn kọ akọle ẹgbẹ wọn ati orukọ ẹni to ku naa si lọwọ wọn, wọn si gbe ọmọ ọlọmọ ti wọn yinbọn mọ ninu lọ sileewosan Ọladayọ fun itọju.

John Wise lorukọ ọmọ ẹgbẹ okunkun to ku ọhun, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹsan-an yii, lo dagbere faye lẹni ọdun mẹtadinlogoji (37),pere.

Pẹlu bọwọ ṣe tẹ wọn yii, CP Edward Ajogun ti paṣẹ pe ki wọn ko wọn lọ sẹka itọpinpin. O kilọ fawọn ọmọkọmọ lati ronupiwada, nitori ẹni tọwọ ijọba ba tẹ ko ni i le royin tan.

Bakan naa lo rọ awọn obi pe ki wọn kilọ fawọn ọmọ wọn, ki kaluku ṣọ ẹgbẹ ti ọmọ rẹ ba wa, nitori ọmọ to ba ṣẹgbẹkẹgbẹ yoo ba ara rẹ nibi ti ko lero ni.

Leave a Reply