Nibi ti Ṣẹgun atawọn ọrẹ ẹ ti n ṣepade oko ole ti wọn fẹẹ lọ lawọn ọlọpaa ka wọn mọ

Gbenga Amos, Abẹokuta

Ṣẹgun Azeez, afurasi adigunjale ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, tọwọ awọn ọlọpaa ẹka ileeṣẹ wọn ni Sango Ọta, ipinlẹ Ogun, ba, ti jẹwọ pe ipade bawọn ṣe fẹẹ ṣaṣeyọri nibi idigunjale ti awọn n gbero lati lọ lawọn n ṣe lọwọ tawọn ọlọpaa fi ka awọn mọ.
Bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe sọ, o ni ọsẹ to kọja yii lọwọ ba afurasi naa, olobo kan lo ta awọn ọlọpaa Sango Ọta, wọn gbọ pe awọn adigunjale fẹẹ waa ṣakọlu si adugbo Agoro, ni Sango, eyi lo mu kawọn ọlọpaa naa tamọra, wọn n ṣọ gbogbo irinsi awọn eeyan ti wọn n lọ ti wọn bọ.
Ẹnu eyi ni wọn wa tawọn aladuugbo kan fi pe wọn pe awọn ṣakiyesi awọn genge kan ti wọn n ṣepade bonkẹlẹ laduugbo Abanikọle. Kia lawọn ọlọpaa ti lọ sibẹ, ṣugbọn bi wọn ṣe yọ si wọn, awọn ẹruuku naa sa lọ, ẹni kan ni wọn ri mu.
Wọn ba ibọn oyinbo pompo kan lọwọ Ṣẹgun, wọn ba katiriiji ọta ibọn ti wọn o ti i yin kan, ati oogun abẹnugọngọ pẹlu.
Wọn ni Ṣẹgun ti jẹwọ pe adigunjale lawọn, eto oko ole kan tawọn fẹẹ lọ lawọn n ṣepade lori ẹ, adugbo Agoro naa lawọn fẹẹ ja lole tọwọ fi ba awọn.
Wọn ti fi afurasi naa ṣọwọ sawọn ọtẹlẹmuyẹ lati ṣiṣẹ iwadii lori ẹ gẹgẹ bi kọmiṣanna ṣe sọ.

Leave a Reply