Iyanu nla lọrọ naa si n jẹ fun gbogbo awọn eeyan to wa nibi ipade kan ti wọn ti n ṣaṣaro lori bi wọn ṣe fẹẹ fi ọba tuntun jẹ niluu Akunnu, ni apa Ila-Oorun ipinlẹ Ondo, Oloye Ọlọrunda Agoyi, ti gbogbo eeyan tun mọ si Ewureni, pẹlu bi baba naa ṣe ṣubu lulẹ, to si gbabẹ ku.
Oloye Aguyi yii wa ninu awọn afọbaje mẹje ti ilu yan lati jokoo ṣepade, ki wọn si fi ọba mi-in jẹ niluu Akunnu-Akoko ti ọba wọn ti waja lati ọdun 2019.
ALAROYE gbọ pe iku ọkunrin naa ki i ṣe oju lasan. Awọn ti o mọ bi ọrọ ọba yiyan naa ṣe n lọ sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe wọn pa ọkunrin naa ni nitori bo ṣe kọ lati ṣe ohun ti awọn kan sọ pe ko ṣe lori ọrọ ọba naa.
Ipade ni wọn n ṣe lọwọ ti ọkunrin naa kan deede ṣubu lulẹ, to si ku patapata. Awọn to mọ baba naa ṣapejuwe rẹ bii eeyan jẹẹjẹ ti ko fẹran wahala rara.