Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ile-ẹjọ Majisireeti to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, ti ni ki ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrinla kan, Marvelous Asefọn, ṣi lọọ maa ṣere lọgba ẹwọn lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an.
Marvelous ni wọn fẹsun kan pe o fi siṣọọsi gun aladuugbo rẹ kan ti wọn porukọ rẹ ni Sunday Ogele, lẹgbẹẹ ikun rẹ lasiko tawọn mejeeji jọ n ja lori obinrin, leyii to ṣokunfa iku ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogun ọhun.
Iṣẹlẹ yii ni wọn lo waye lagbegbe Kanmu, niluu Ọka Akoko, ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2023 ta a wa yii.
Ẹsun ọhun ni Agbefọba, Martins Olowofẹsọ, ni iwa ti ọmọkunrin naa hu ta ko abala okoolelọọọdunrun din mẹrin (316) ati okoolelọọọdunrun din ẹyọ kan (319) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Olowofẹsọ waa rọ ile-ẹjọ lati buwọ lu ẹbẹ fífi olujẹjọ naa pamọ sinu ọgba ẹwọn titi ti wọn yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.
Agbejọro fun olujẹjọ ninu ẹbẹ tirẹ ni ki adajọ siju aanu wo onibaara oun, nitori igbesẹ ti n lọ labẹnu laarin awọn ẹbi ti ọrọ kan lati yanju ọrọ naa nitubi inubi.
Ṣugbọn ninu ọrọ Ọgbẹni Ogele to jẹ baba oloogbe, o ni ko ti i si ajọsọ ọrọ kankan laarin oun atawọn ẹbi Marvelous ti wọn fẹsun ipaniyan kan.
Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Fọlaṣade Aduroja ni ki ọmọkunrin naa ṣi wa lọgba ẹwọn titi di ọjọ kọkanla, oṣu Kẹfa, ọdun 2023, nigba ti igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.