Nibi ti wọn ti n le awọn onifayawọ, aṣọbode yinbọn pa eeyan marun-un niluu Isẹyin

Eeyan marun-un lawọn aṣọbode ilẹ wa tun yinbọn pa ni Ọjọbọ, Tosidee, ọsẹ yii, niluu Isẹyin, lasiko ti awọn ati awọn onifayawọ kọju ija sira wọn.

ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ naa waye lasiko ti awọn aṣọbode naa ri mọto jiipu kan to ko irẹsi ti wọn fura si pe o jẹ irẹsi ilẹ okeere. Bi wọn ṣe ri mọto jiipu ọhun ni wọn ti bẹrẹ si i le e, bi wọn ṣe n le e naa ni wọn n yinbọn ki wọn le fi da a duro.

Ibọn ti wọn n yin lai besu bẹgba yii lo lọọ ba marun-un ninu awọn ara adugbo naa ti wọn n ṣe ajọyọ ayẹyẹ ọdun Itunu aawẹ jẹẹjẹ wọn, ki awọn araalu si too mohun to n ṣẹlẹ, eeyan marun-un nibọn ti wọn yin naa ti ba, ti wọn si ku lẹsẹkẹsẹ.

Iṣẹlẹ ibanujẹ yii lo mu ki awọn ọdọ ilu naa lọọ ju ina si ileeṣẹ kọsitọọmu to wa niluu Isẹyin, nibi ti wọn ti dana sun awọn ọkọ to wa nibẹ.

Awọn eeyan ilu naa ni o ti di gbogbo igba awọn aṣọbode yii. Aimọye ẹmi alaiṣẹ ni wọn ti fi ṣofo lori pe wọn n le awọn onifayawọ to n ko irẹsi wọle.

Leave a Reply