Nibi t’ọba alaye ti n sa fun awọn ajinigbe ni wọn ti yinbọn fun un l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Awọn agbebọn kan tawọn eeyan fura si bii ajinigbe ti yinbọn lu Elewu tilu Ewu-Ekiti, nijọba ibilẹ Ilejemeje, Ọba Adetutu Ajayi.

Nnkan bii aago meje alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, niṣẹlẹ naa waye nigba ti ọba alaye ọhun n lọ si Ayetoro-Ekiti lati ilu ẹ, iṣẹlẹ ọhun si ti sọ kabiyesi di ero ileewosan.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ṣe lawọn agbebọn yii deede yọ si Ọba Alabi, nigba to si n gbiyanju lati sa fun wọn ni wọn dabọn bo mọto ẹ, bẹẹ ni ọta ba a ni ẹsẹ, apa ati ikun.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ọlọpaa Ekiti, ASP Sunday Abutu, fẹdun ọkan sọrọ pe iṣẹ takuntakun lawọn ẹṣọ laabo n ṣe lọwọlọwọ, ṣugbọn iru iṣẹlẹ bẹẹ tun pada waye.

Abutu ni awọn ọlọpaa, ikọ Amọtẹkun, fijilante, ọdẹ, awọn oloye, ẹgbẹ onimọto, ẹgbẹ ọlọkada, awọn agbẹ atawọn tọrọ kan lẹka eto aabo lo n pawọ-pọ wa awọn eeyan naa kaakiri awọn igbo to wa l’Ekiti, iyalẹnu lo si jẹ bi wọn tun ṣe gba ọna mi-in yọ, ṣugbọn ọwọ yoo pada tẹ wọn.

O waa ni eyi ko ni i fa irẹwẹsi sọkan awọn ẹṣọ alaabo, gbogbo ibi tawọn amookunṣikan ọhun ba si sapamọ si lawọn yoo lọọ ka wọn mọ nitori Ekiti ki i ṣe ile ọdaran.

Leave a Reply