*Idi abajọ ree o
Inu Ọgagun Muritala Muhammed ko dun rara si ohun ti Ọgagun agba Yakubu Gowon, olori ijọba Naijiria nigba naa, ṣe fun Theophilus Akindele yii. Muritala fẹ ki wọn le ọkunrin naa kuro lẹnu iṣẹ ijọba pata ni, ko fẹ idaduro fungba diẹ ti Gowon ṣe fun un. Loju Muritala, bii igba ti Gowon n fi aaye agbaju gba ọkunrin olori ileeṣẹ eto ibanisọrọ yii ni, ati pe oun lo n fun un layọ yọ, to fi jẹ ki ọkunrin naa maa foju di oun odidi minisita. Bi o ba jẹ oun Muritala ni olori ijọba, iru awọn eeyan bii Akindele to n fa wahala, to si jọ ara rẹ loju yii, oun yoo yọ ọ danu bii ẹni to yọ jiga ni, ti kinni kan ko si ni i ti idi rẹ yọ. Ṣugbọn Gowon ko ṣe bẹẹ, nitori o mọ lọkan ara rẹ pe ni tododo, Akindele yii ko ṣe kinni kan. Gbogbo ohun ti ọkunrin naa ṣe, Gowon mọ pe fun anfaani gbogbo Naijiria ni, ohun ti ko si ni i jẹ ki Naijiria fowo ṣofo nipa gbigbe iṣẹ fun ITT ni.
Ṣugbọn ko le sọ bẹẹ loju awọn ọmọọṣẹ rẹ ninu iṣẹ ologun ti wọn jọ n ṣejọba. O mọ pe MKO Abiọla ni olori ileeṣẹ ITT ni Naijiria, oun ni aṣoju wọn, ati pe Abiọla yii, ọrẹ timọtimọ lo jẹ fun Muritala, boya ni ko si jẹ wọn jọ mọ ohun to n lọ nileeṣẹ naa ni. Bẹẹ Muritala ni ero lẹyin ninu awọn ọga ṣọja ti wọn jọ n ṣejọba ologun, boun ba si huwa kan ti ko tẹ wọn lọrun, wọn le ditẹ mọ oun, iyẹn bi wọn ko ba tilẹ gba ijọba naa lọwọ oun. Ati pe ki i kuku tilẹ i ṣe oni, ki i ṣe ana, ti Muritala ti maa n gbo Gowon lẹnu nibi ipade nla yii, bi inu ba si bi i tan pata, ko si ohun ti ko le ṣe. Ohun to jẹ ki Gowon ni ki wọn da Akindele duro fungba diẹ lẹnu iṣẹ ree, nitori ko fẹẹ ri ija Muritala ati awọn eeyan rẹ, bẹẹ si ni ko le le Akindele kuro lẹnu iṣẹ patapata, nigba to mọ pe ọkunrin naa ko ṣe nnkan kan ti ko dara, iṣẹ tirẹ lo n ṣe gẹgẹ bii ojulowo oṣiṣẹ ijọba.
Nitori pe wọn mọ pe gbogbo ohun ti awọn ṣe naa ko dara, ko gbọdọ lu jade, itiju ati abuku ni yoo jẹ fun gbogbo awọn ti wọn n ṣejọba naa, iyẹn ni Gowon ṣe kilọ fun Akindele pe ohun to ṣẹlẹ yii ko gbọdọ jade ninu beba tabi nileeṣẹ iroyin kankan. Akindele ni oun ti gbọ, ko si ṣe meni ko ṣe meji, o ko faili ati awọn iwe rẹ, o jade nipade, o gba ọọfiisi rẹ lọ. Nigba to de ọọfiisi rẹ paapaa, ko le ba ẹni kan sọrọ, o kan sọ fun akọwe rẹ pe ko pa gbogbo ipade to ni rẹ pata, ko sọ fun awọn ti awọn jọ fẹẹ ṣepade pe oun le ma ri aaye ri wọn fun igba pipẹ. Nigba ti akọwe rẹ beere pe nigba wo ni koun waa da fun wọn pe ki wọn wa, Akindele sọ fun un pe ko ma da igba kankan fun wọn o, nitori oun ko mọ igba toun le pada si ẹnu iṣẹ yii, pe ijọba apapọ ti da oun duro fungba diẹ na, oun ko si mọ ọjọ ti wọn yoo pe oun pada pe koun waa bẹrẹ iṣẹ oun.
Bo ti sọ bẹẹ lo palẹ ẹru rẹ mọ, n lo ba lọ. Ṣugbọn ni fẹẹrẹ ti ilẹ mọ lọjọ keji, olori ileeṣẹ Daily Times igba naa, Alaaji Babatunde Jọsẹ, ẹni to n gbe ni bii ile kẹta si ile Akindele gba ilẹkun ile wọn lati wọle, wọn si sare ji Akindele loju oorun fun un. Nigba to jade si i ni palọ ti iyẹn jokoo si, ohun ti Jọsẹ kọkọ beere ni pe ki lo ṣẹlẹ nibi iṣẹ wọn, bẹẹ lo fa iwe naa yọ gadagba, ti wọn si ti kọ ọ sibẹ pe ija agba laarin Muritala ati Akindele ti jẹ ki wọn da Akindele duro lẹnu iṣẹ fungba diẹ na o. O ya Akindele lẹnu, o si ya Jọse naa lẹnu nigba ti Akindele ṣalaye fun un pe bi ọrọ se jẹ naa ree, ṣugbọn oun ko mọ bi kinni naa ti de inu beba. Nibi ti wọn ti n sọrọ lọwọ ni Gowon ti tẹlifoonu si i, iyẹn si Akindele, pe oun ti ri iṣẹ ọwọ rẹ, ko maa reti awọn ṣọja ti yoo waa gbe e ni ile rẹ laipẹ rara. Bi Jọse ti gbọ bẹẹ loun sare jade, ko fẹ kawọn ṣọja ba oun nile ẹ.
Akindele jokoo sile ẹ, o n reti awọn ṣọja, awọn ọrẹ rẹ ti wọn si ti gbọ ọrọ yii bẹrẹ si i pe pe ki lo de, ṣe ko si nnkan kan, wọn si n ba a daro ohun to ṣẹlẹ si i. Awọn kan ti wọn gbọ pe Gowon n ran ṣọja bọ waa gbe e ni ko tete sa jade nile ẹ, ko ma duro rara.
Akindle taku, o loun ko le sa jade ninu ile oun nigba toun ko ṣe ohun kan. Oun ko fun oniroyin ni iroyin ohun to ṣẹlẹ, koda oun o ti i fi ẹnu ara oun sọ ọrọ naa fun ẹnikan kan titi ti Jọsẹ fi de ọdọ oun, to fi mu iwe wa, ki waa ni koun maa sa lọ fun, bi awọn ṣọja ba fẹẹ wa ki wọn wa jare. Ṣugbọn bii wakati meji kọja, ko ri ṣọja kankan ko wa, titi di bii wakati mẹrin. Lẹyin naa ni Gowon tun tẹlifoonu si i pada funra ẹ, o ni ko maa bọ ko waa ri oun ni ọọfiisi oun. Akindele ko fẹẹ lọ, o si sọ bẹẹ fun Gowon, o ni oun ko le jẹ ki awọn ṣọja mu oun nibẹ ki ẹnikan ma mọ, to ba fẹẹ mu oun, ki wọn waa gbe oun nile oun ni.
Gowon fi i rẹrin-in ni, o ni bo ba ṣe pe oun fẹẹ fi ṣọja gbe e ni, oun ko ni i maa pe e mọ, ile rẹ naa ni wọn yoo ti gbe e. Ni Akindele ba lọọ ba Gowon. Nigba to de ọhun, Gowon ni iwadii awọn ti fi han pe ki i ṣe oun lo ba ẹnikẹni sọrọ lori ọrọ yii, pe oniroyin Daily Times kan to ti n gbọ hunrun-hunrun lori ohun to n lọ nileeṣẹ naa tẹlẹ wa nibẹ nigba ti Akindele n sọ fun akọwe rẹ pe wọn ti da oun duro fun igba diẹ na, oniroyin yii lo si fi eeji kun ẹẹta gẹgẹ bii ohun to ti gbọ tẹlẹ, oun lo sare lọọ gbe iroyin naa jade. O ni nitori bẹẹ, ki Akindlee ma binu, ko maa pada lọ sile rẹ. O daju pe ki i ṣe nitori eleyii ni Gowon ṣe pe Akindele, nitori bo ba jẹ ohun to fẹẹ sọ fun un naa niyi, ko si ohun ti ko ṣe le sọ ọ ni ori tẹlifoonu, ṣugbọn lati fi ọgbọn tu Akindele ninu ni, ko si jẹ ko mọ pe ko si ohun toun le ṣe si ọrọ to wa nilẹ naa ju eyi ti oun ṣe yẹn lọ ni.
Akindele pada si ile rẹ, aaye waa gba Muritala lati ṣe ohun ti wọn fẹẹ ṣe. Loju-ẹsẹ lo pada si ileeṣẹ rẹ, o si gbe igbimọ mi-in dide lati ṣe atunṣe awọn iwe ti wọn kọ lọjọsi lori ọrọ iṣẹ ti wọn fẹẹ gbe fun ITT yii kan naa, iṣẹ ti wọn tori rẹ le Akindele. Iyatọ to wa ninu igbimọ eleyii ni pe akọwe agba fun ileeṣẹ naa, Ọgbẹni Williams, ati olori ẹka eto ibanisọrọ, Ọgbẹni Lasọde, ni wọn wa nidii eto naa bayii, ohun ti wọn ba fẹ ni wọn si le ṣe. Gbogbo awọn ti wọn wa ninu igbimọ naa lọjọsi ti wọn tẹle Akindele lori ọrọ yii ni wọn ko pe sinu igbimọ naa mọ, nigba ti wọn si ṣepade wọn, kia ni wọn fi ọwọ si iṣẹ yii, wọn ni ki ITT ko irinṣẹ naa wa fawọn, nitori yoo wulo gan-an, yoo si mu eto ibanisọrọ awọn gbooro si i ni Naijiria. Iwe yii ni Muritala gbe lọ siwaju igbimọ awọn ologun apapọ pe ki wọn fọwọ si i ki ITT le bẹrẹ iṣẹ wọn, nitori iṣẹ naa ti falẹ fun ọjọ pipẹ.
Kia ni igbimọ awọn alaṣẹ ijọba apapọ ti fi ọwọ si iṣẹ naa nibi ipade wọn loṣu kin-in-ni, ọdun 1975, nigba to si di ibẹrẹ oṣu keji, ijọba Naijiria ati ileeṣẹ ITT fọwọ si iwe adehun yii, wọn ni ki ITT bẹrẹ iṣẹ wọn. Gẹgẹ bi a ti wi tẹlẹ, miliọnu lọna irinwo ati aabọ o le ni owo iṣẹ yii, bẹẹ ni Akindele ṣe ẹkunrẹre alaye pe bii ilọpọ mẹwaa iye to yẹ ki wọn ṣe iṣẹ naa ni wọn kọ wa yii, iyẹn ni pe bii ogoji (40) miliọnu naira lo yẹ ki wọn fi ṣe iṣẹ yii, ṣugbọn ITT, ileeṣẹ awọn Abiọla, gba irinwo (400) miliọnu o le, ọọkan ibi yii ni owo Abiọla si ti yarọ, owo naa de digbidigbi ti oun naa ko si mọ ohun toun yoo fi i ṣe ni, owo naa ti pọ ju. Ọsẹ akọkọ ninu oṣu keji ni wọn gbe iṣẹ yii fun awọn ITT, ọsẹ yẹn naa ni wọn kọwe si Akindele pe to ba ti di ọjọ kẹrinla, oṣu keji, ni 1975 kan naa, ko pada si ẹnu iṣẹ rẹ, ṣe wọn ti gbe iṣẹ fun ITT, ITT ti gbowo iṣẹ wọn, ọkan Muritala si ti balẹ. Nnkan nla gbaa ni!
Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.
Asiko ti koja lori ati maa ranti awon oro jati-jati bayi, asiko yi je asiko elege fun Iran Yoruba nitorina oro meji ni o yeki a ma so bayi:
(Eni) Bi ao se datura bi Orile Ede
(Eji) Bi ao se paramo last gbe ogun ti awon Fulani ati daran daran onisunmi ki won ma gba ole wa lowo wa.
(Eta) Bi aose gbogun ti awon agbehin before laarin wa
Abiola at Awolowo ti di Orisha fun ile Yoruba ki Oluwa ki o Tewin si afefe rere. Toto o se bi owe eyin agba: BI A KOBA GBAGBE ORO ANA AKONI RI ENIKAN A BA SERE.
Gbogbo rugudu ti oro Oselu desire laarin awon Baba wa ti ti ohun igbagbe. Ejeki a se imo wa lokan