Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Iku ọmọdekunrin ẹni ọdun mejila, atwọn meji ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa, to jẹ ọmọ ileewe girama Ayọ Daramọla, to wa ni Ijan-Ekiti, nijọba ibilẹ Gbonyin, nipinlẹ Ekiti, ti da wahala silẹ.
Iṣẹlẹ to waye laaarọ Ọjọbọ, Wesidee, ni deedee aago mẹsan-an aabọ ọhun lo bi awọn ẹgbẹ ọmọdekunrin to wa ni kilaasi keji nileewe naa ati mọlẹbi rẹ ninu ti wọn fi gun le iwọde kan, eyi to da igbokegbodo ọkọ duro loju ọna naa, eyi to fa a ti ọpọlọpọ awọn to n rin irin–ajo ati awọn to n lọ sibi iṣẹ ko ṣe ri aaye kọja.
Ijamba yii ṣẹlẹ niwaju oko kan ti wọn n pe ni Agọ, ki wọn too de ilu Ijan-Ekiti, lojuko kan ti ko dara loju ọna naa.
Ẹnikan tọrọ naa ṣoju rẹ, to ba ALAROYE sọrọ sọ pe ọmọdekunrin ti ọkọ akoyọyọ pa yii atawọn meji to ku ti wọn farapa yii je olugbe Agọ, ni oko kan to wa loju ọna naa, wọn n lọ sileewe laaarọ ọjọ iṣẹlẹ yii ni.
O ṣalaye pe ọmọkunrin ti ọkọ akoyọyọ pa yii ati awọn meji yooku ti wọn fara pa yii jẹ ọmọ iya kan naa. O ni bi wọn ṣe ri ọkọ akoyọyọ to ko yeepẹ yii ni wọn n ṣẹwọ si i pe ko ṣaanu awọn, ko gbe awọn siwaju.
Bi wọn ṣe n lọ ninu irin–ajo naa ni dẹrẹba ọkọ yii ẹfẹ yẹra fun koto kan to wa loju ọna naa, eyi o mu ki ọkọ akoyọyọ yii takiti, to si ṣubu lojiji.
Ọkan lara awọn ọmọ ileewe yii ni ori rẹ fọn ka, to si ku lojiji, nigba ti wọn ko awọn meji to ku lọ silewwosan fun itọju.
Nigba to n sọrọ lori ọrọ naa, Alukoro ajọ ẹṣọ oju popo nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Taiwo Ojo, sọ pe loootọ niṣẹlẹ oun ṣẹlẹ.
O ṣalaye pe awọn meji to ku ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa ni wọn ti ge ẹsẹ wọn mejeeji nileewosan ijọba nipinlẹ Ekiti.
Alukoro ajọ oju popo naa sọ pe awọn ẹṣọ oju popo lo lọ si ojuko naa lati lọọ doola ẹmi awọn ọmọleewe yii. Bakan naa lo ni wọn ti gbe oku ẹni kan to ku ninu ijamba naa lọ si ile igbokuu- pamọ si.
O rọ gbogbo awakọ pe ki wọn maa fi suru wakọ ni gbogbo igba ti wọn ba wa ni oju popo.