N’Ileṣa, owo ‘ọmọ onilẹ’ di wahala laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, eeyan marun-un lo ku

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ṣe lawọn eeyan ilu Ileṣa, nipinlẹ Ọṣun, n gbe tifura-tifura bayii latari wahala kan to bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun oriṣii meji nibẹ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ fidi rẹ mulẹ pe eeyan marun-un ni wọn ti gbẹmi mi laarin ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, si Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii.

Agbegbe kan ti wọn n pe ni Okutu Ope, niluu Ileṣa, ni wahala naa ti kọkọ bẹrẹ lọjọ Furaidee, ko too di eyi to n ran kaakiri.

A gbọ pe awọn igun mejeeji ẹgbẹ okunkun naa lọ sibi ile kan ti wọn n kọ lọwọ ni Okutu-Ope lati gba owo ọmọ onilẹ ki wọn too maa ba iṣẹ lọ nibẹ.

Lẹyin ti wọn gba owo naa tan ni wahala bẹ silẹ lori bi wọn aa ṣe pin owo ọhun, inu wahala yii ni wọn pa ọkan lara wọn ti wọn pe ni China, bayii ni awọn ti wọn jẹ igun ti oloogbe naa bẹrẹ si i ṣoro bii agbọn kaakiri.

A gbọ pe awọn ọlọpaa gbe oku China lalẹ ọjọ naa, ṣugbọn titi ti ilẹ fi mọ lọjọ Satide ni wọn n dọdẹ ara wọn kaakiri ilu Ileṣa, ti awọn abala keji naa si tun pa ẹni kan.

Ẹnikan to ba Alaroye sọrọ lagbegbe naa, ṣugbọn to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ṣalaye pe awọn araalu ti ko mọwọ mẹsẹ mẹta ni wọn ba iṣẹlẹ naa lọ, lara wọn si ni obinrin kan to n bọ lati iṣọ-oru nidaaji ọjọ Satide.

Ninu ọrọ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, o ni Kọmiṣanna ọlọpaa, Wale Ọlọkọde, yoo lọ siluu Ileṣa lọjọ Aiku, Sannde, lati lọọ wo nnkan to n ṣẹlẹ gan-an.

Ọpalọla sọ pe lẹyin eyi ni ileeṣẹ ọlọpaa too le sọ ni pato iye ẹmi to sọnu ninu wahala naa.

Leave a Reply