Nitori aabọ owo-osu ti Akeredolu n san, dokita marunlelọgọrun-un binu kọwe fiṣẹ silẹ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn dokita bii marunlelọgọrun-un ni wọn ti binu kọwe fisẹ silẹ latari aabọ owo-osu ti Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, n san fawọn oṣiṣẹ.

Alaga ẹgbẹ awọn dokita nipinlẹ Ondo, Dokita Ọlrọrunfẹmi Ọwa, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Yatọ sawọn to sẹsẹ kọwe fipo silẹ, awọn agba dokita to to bii aadọta lo ni wọn ti kọkọ lọ, ti ko si ti i si igbesẹ lati ọdọ ijọba lati gba awọn mi-in rọpo wọn.

O ni ọpọ awọn ileewosan ijọba, nibi ti awọn dokita bii mẹfa si mẹjọ ti n bojuto awọn alaisan tẹlẹ ni wọn ko ni ju ẹyọ kan tabi meji mọ to n ṣiṣẹ bayii.

Dokita Awẹ ni ko si bi eto ilera to muna doko ṣe fẹẹ waye lawọn ọsibitu to wa nipinlẹ Ondo tijọba ba fi kuna lati tete wa wa nnkan ṣe lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply