Jide Alabi
Ọfiisi ajọ EFCC ni ọkan ninu awọn ọmọ Aṣiwaju Bọla Tinubu, iyẹn Ọgbẹni Babatunde Fowler, ti n sọ ohun to mọ bayii nipa ẹsun ọgọrun-un biliọnu naira, owo-ori ti ileeṣẹ Alpha Beta kọ lati san fun ijọba Eko.
Ọgbẹni Babatunde Fowler yii ni ọga agba tẹlẹ fun ileeṣẹ to n pawo wọle fun ijọba Eko labẹle (IGR). Oun naa si tun ni ọga agba tẹlẹ fun ileeṣẹ ijọba apapọ to n pawo wọle (FIRS)
Ohun ti wọn tori ẹ pe Fowler si ọfiisi wọn ni bi ileeṣẹ Alpha Beta ko ṣe san owo-ori to yẹ fun ijọba Eko, ati pe Fowler yii gẹgẹ bii ọga agba nileeṣẹ to n ba ijọba Eko gbowo nigba yẹn ni lati sọ ohun to mọ nipa ọrọ ọhun.
Mọnde, ọjọ Aje, ọsẹ yii, ni Babatunde Fowler, lọọ yọju si ajọ EFCC, lẹyin ti wọn fiwe pe e.
Ṣaaju asiko yii ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Alpha Beta, Dapọ Apara, ti kọwe si ajọ EFCC, nibi to ti fẹsun kan Babatunde Fowler pe ki wọn mu ọkunrin naa daadaa, nitori oun naa ni ipa to ko lori bi ileeṣẹ Alpha Beta ko ṣe san owo to to ọgọrun-un biliọnu naira to yẹ ko san gẹgẹ bii owo-ori fun ijọba Eko.
Apara, sọ pe o pẹ ti ileeṣẹ to gbaṣẹ lati maa dari gbogbo bi ijọba Eko ṣe n pawo wọle ti n ṣe oriṣiiriṣi aṣemaṣe yii, ti awọn oloṣelu to ni in si n lo o lati maa fi kowo jẹ.
Ọdun 2018 ni Apara ti kọwe yii ranṣẹ si EFCC, ṣugbọn ọjọ Aje, Mọnde, ni Fowler lọọ yọju si wọn nibẹ. Agbẹnusọ fun ajọ EFCC, Wilson Uwujaren sọ pe Fowler wa nileese awọn bayii, nibi to ti n dahun awọn ibeere lori ohun to mọ nipa ẹsun ọgọrun-un biliọnu naira ti Alpha Beta jẹ ijọba Eko.