Nitori arun korona, o ṣee ṣe ka tun kede ofin konilegbele- Ihekweazu

 Ileeṣẹ ijọba to n ri si fifi opin si itankalẹ arun ti sọ pe o ṣee ṣe ki awọn tun kede ofin konilegbele nitori arun koronafairọọsi lẹẹkan si i.

Ọga agba fun ajọ ọhun, Dokita Chikwe Ihekweazu, lo sọrọ yii fawọn oniroyin nibi apejọ kan ti ajọ to n samojuto eto isinlu ẹni (NYSC) gbe kalẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii niluu Abuja.

O ni o ṣe pataki ki awọn eeyan orile-ede yii tẹle ofin ati ilana lati pa ara wọn mọ kuro lọwọ itankalẹ arun koronafairọọsi, nitori arun ọhun ko ti i kuro nilẹ patapata.

O ni gbogbo eto ati ilana ti ijọba la kalẹ lati fi fopin si i lawọn eeyan ṣi gbọdọ maa pamọ, ti wọn ko ba tun fẹ ki ijọba paṣẹ pe ki kaluku jokoo sile.

Chikwe ti waa kilọ pe ti itakanlẹ arun koronafairọọsi ba tun lọọ lagbara si i, ijọba ko ni i wo o lẹẹmeji ko too tun kede ofin konile-gbele.

 

 

Leave a Reply