Nitori Aunty Ramota, ija nla bẹ silẹ laarin Iya Ereko ati oṣere mi-in, ọpẹlọpẹ Mr Latin

Kazeem Aderounmu

Fidio kan lo kọkọ wa lori ikanni ẹrọ ayelujara, Instagiraamu ti Jamiu Azeez, ọkan lara awọn ọdọmọde onitiata to n ṣe daadaa lasiko yii. Ẹkun nla ni ọmọkunrin yii n sun yọbọ, ohun to si sọ pe o ṣẹlẹ soun ko ju bi awọn eeyan kan ṣe ji itan ‘Ọkọ Ramọta’ to sọ pe oun ṣẹṣẹ ya si sinima ẹ ti ko ti i jade. O ni ẹnikan lara awọn oṣere ẹlẹgbẹ oun n gbiyanju lati ya iru ẹ, to si lo awọn oṣere to lorukọ nla nla.

Ohun to pa ọkunrin yii lẹkun gẹgẹ bo ṣe sọ ọ sinu fidio  ọhun ni pe bi oun ṣe ta dukia, bẹẹ loun yawo, ki sinima ‘Ọkọ Ramọta’ too ṣee ṣe.

Ohun ti Jamiu Azeez sọ ree pẹlu omije loju, ki oloju si too ṣẹ ẹ, niṣe ni awọn eeyan bẹrẹ si i ṣepe le ẹni to ṣiṣẹ ibi yii fun un. Lara awọn oṣere ẹlẹgbẹ ẹ paapaa ṣeleri lati ba tọhun fa a, ti wọn lawọn yoo ba a gba lọọya ti yoo ba a rojọ niwaju adajọ.

Ṣa o, nigba ti yoo fi to wakati meloo kan sigba ti fidio Jamiu Azeez jade sita ni ọkan lara awọn iya agbalagba toun naa jẹ oṣere fiimu Yoruba, Arabinrin Morẹnikeji Alausa, ẹni ti gbogbo eeyan tun mọ si Mama Ereko naa gbe tiẹ jade, ninu eyi ti mama agbalagba yii ti ṣẹ epe nla le ara ẹ, bẹẹ lo tun ṣẹ ẹ le Jamiu Azeez.

Ohun ti iya yii sọ ni pe oun ko tete mọ pe oun ni Jamiu n ba a wi nigba ti oun ko ṣiṣẹ ibi kankan fun un, ati pe awọn oṣere kan lo pe oun, ti wọn sọ pe mama agbalagba kan lo ji itan Jamiu, ṣugbọn ti oun ko kọbi-ara si i nigba ti oun ko hu iru iwa bẹẹ ni toun.

Ninu ọrọ Mama Ereko ni iya yii ti sọ pe, “Emi o tiẹ tete mọ pe emi ni Jamiu Azeez n ba wi pe mo ji itan ti oun fi ṣe sinima gbe. Loootọ ni mo fẹẹ lo Aunti Ramọta sinu fiimu ti mo fẹẹ ya. Ipa ọmọọdọ gan-an lo maa ko ninu sinima ọhun. Iyawo alarede lo ṣe ninu sinima Jamiu, bawo lo ṣe waa jọ ara wọn pẹlu temi.

“Yatọ si eyi, fiimu ọlọba lemi fẹẹ ya ni temi, ki i ṣe iru ohun ti Jamiu loun ya. Ṣaaju asiko yẹn lemi naa ti ri fidio to ṣe, nibi to ti n sunkun, bẹẹ ni mo ṣepe fun ẹni to ṣeru ẹ fun un, lai mọ pe emi gan-an lo n fẹsun kan, ti gbogbo aye n ṣepe nla nla, ṣugbọn epe yẹn ko le mu mi o. Iyalẹnu nla lo jẹ nigba ti Mista Latin, ẹni ti i ṣe olori ẹgbẹ wa pe mi to beere pe ki lo ṣẹlẹ laarin emi ati Jamiu, O ni ọmọ yẹn fẹjọ sun pe emi ni mo ji fiimu oun kọ. Latijọ ti mo ti n ṣe sinima, iru ẹ ko ṣẹlẹ si mi ri, nitori emi naa ki i ṣe ọmọde mọ nidii iṣẹ yii.

“Jamiu ba mi lorukọ jẹ ni o, nitori ohun ti mi o ṣe lo fẹsun ẹ kan mi. Lati ọdun to kọja ni mo ti fẹẹ ya sinima yẹn ki Ọdunlade Adekọla too sọ pe ki n jẹ ko di inu oṣu keji, yii. Okiki Afọlayan naa lo fẹẹ ba mi dari ẹ. Gbogbo awọn eeyan bii Afeez Ẹniọla, Ogogo; Pasuma; Wunmi Toriọla ati Mide Martins ni wọn mọ nipa itan inu fiimu ọhun.

“Ohun to si ṣe yẹn, mo ṣetan bayii lati gbe ara mi ṣepe ati Jamiu naa, ti mo ba mọ nnkan kan nipa fiimu ‘Ọkọ Ramọta’ yatọ si ori Instagiraamu ti wọn n gbe e si kiri, gbogbo ohun ti mo ba n wa nile aye mi ki n ma ri i. Gbogbo ohun ti mo ba dawọ-le nidii isẹ tiata yii, ki n ma ri i, amọ ti ko ba jẹ bẹẹ, ti mi o mọ nnkan kan ti mi o tiẹ rokan lo sibẹ, ti mi o mọ nnkan kan nipa sitori ẹ, to waa n ba mi lorukọ jẹ kiri, Jamiu, Ọlọrun a ba ẹ lorukọ jẹ lati aye dọrun. Gbogbo epe ti o ṣẹ yẹn, ori ẹ lo maa da le. Gbogbo epe ti awọn agbodegba ẹ ṣẹ, ori ẹ lo maa da le, adabi ti mo ba mọ nnkan kan nipa ẹ. O waa lọọ fẹjọ mi sun awọn olori wa, ṣe o n ṣiere ni…. Jamiu, mo nifẹẹ rẹ gan-an, ṣugbọn o ti tẹ lọwọ mi bayii, bẹẹ lo tun tẹ lọwọ aye…”

Bi mama yẹn ṣe ṣepe le Jamiu Azeez ree o, ṣugbọn bi ọrọ ọhun ṣe n lọ lo mu awọn oloye ẹgbẹ wọn da si i, ti Mista Latin, iyẹn Ọgbẹni Bọlaji Amusan, pẹlu Azeez ati Sisi Quaidri si gbe fidio kan jade.

Ninu fidio naa ni Mista Latin ti sọ pe awọn ti yanju iṣẹlẹ ọhun, bẹẹ ni Jamiu Azeez naa sọ pe oun ti pe Mama Ereko, bẹẹ loun ti bẹ iya ki wọn ma binu aṣiṣe loun ṣe, ati pe gbogbo epe ti mama naa ṣẹ, adura ni, ko si wahala kankan mọ laarin awọn.

Nibi ti wọn fi ọrọ ọhun ti si niyẹn o, ṣugbọn oju oriṣiiriṣii lawọn eeyan fi wo o, paapaa awọn ti wọn wo fidio mejeeji.

Bawọn kan ṣe n sọ pe mama yẹn ti binu ju, nitori epe nla nla to ṣẹ fun ọmọ ọlọmọ, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe ko yẹ ki Jamiu naa sare bẹ sita bayii lai wadii daadaa.

Awọn eeyan mi-in paapaa tun sọ pe lara awọn eeyan wọn naa lo da wahala ọhun silẹ. Wọn ni dajudaju, ẹnikan ninu awọn oṣere to mọ pe Mama Ereko naa fẹẹ lo Aunti Ramọta lo maa pe Jamiu, ki ọrọ ọhun too di iṣu ata yan-an yan-an.

Leave a Reply