Nitori awọn aṣofin ti wọn yọ nipo l’Ondo, ile-ẹjọ fiwe pe olori ile-igbimọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Olori ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, Ọnarebu David Bamidele Ọlẹyẹlogun, ti gba iwe waa sọ tẹnu ẹ lati ile-ẹjọ giga ipinlẹ naa lori ọrọ awọn aṣofin mẹrin ti wọn da duro lati nnkan bii oṣu meji sẹyin.

Abẹnugan ọhun ni wọn lo ṣee ṣe ko foju wina ofin lori bo ṣe kọ lati da awọn aṣofin mẹrin ti wọn yọ nipo pada ni ibamu pẹlu asẹ tile-ẹjọ pa.

Lati osu bii mẹrin sẹyin lọkan-o-jọkan wahala ti n su yọ laarin awọn adari ile-igbimọ ọhun atawọn aṣofin mẹsan-an ti wọn n ṣatilẹyin fun Igbakeji Gomina, Ọnarebu Agboọla Ajayi.

Ninu rogbodiyan yii ni wọn ti kede pe wọn ti da mẹrin ninu awọn aṣofin naa duro lori ẹsun ṣiṣe aigbọran si ilana ati ofin wọn.

Ile-ẹjọ giga to wa niluu Akurẹ lo kọkọ da awọn aṣofin ọhun, Irọju Ogundeji, Favour Tomowewo, Tọmide Akinribido ati Wale Williams lare ninu ẹjọ ọtọọtọ ti wọn pe ta ko bi ile ṣe da wọn duro.

Bi ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ṣe da ẹjọ tawọn adari ile pe ta ko idajọ naa nu nile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lo gbo awọn aṣofin wọnyi laya ti wọn fi wa sile-aṣofin naa l’Ọjọruu, Wẹsidee ọṣẹ to kọja.

Lẹyin ti wọn ti sa gbogbo ipa wọn, ṣugbọn ti wọn ko fun wọn laaye ati wọle ni wọn binu pada si kootu, ti wọn si lọọ fẹjọ Ọlẹyẹlogun sun fun ṣiṣe afojudi si asẹ tile-ẹjọ pa.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, la gbọ pe wọn waa fun olori awọn aṣofin naa ni fọọmu kan ti wọn n pe ni ’48’ eyi ti wọn lo tumọ si ẹsun siṣe afojudi si aṣẹ ile-ẹjọ.

Leave a Reply