Nitori ayẹyẹ ‘Ikarẹ day’, awọn ọba alaye meji kọju ija sira wọn

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ija agba to n waye laarin Olukarẹ ati Ọwa Ale tilu Ikarẹ Akoko, tun gbọna mi-in yọ lọjọ Abamẹta, Satide ọsẹ to kọja, pẹlu bi wọn ṣe yinbọn pa eeyan meji, ti awọn mi-in si tun fara gbọta ninu rogbodiyan to waye ọhun.

Ṣe lawọn alatilẹyin awọn ọba mejeeji, iyẹn Olukarẹ ti Ikarẹ Akoko, Ọba Saliu Akadri Momoh, ati Ọwa Ale ti Ikarẹ, Ọba Adeleke Adefẹmi Adegbitẹ, n di ẹbi rogbodiyan ọhun le ara wọn lori, bi awọn igun Onikarẹ ṣe n lọgun pe awọn ọmọlẹyin Ọwa Ale lo kọkọ bẹrẹ akọlu naa lawọn ti Ọwa Ale ni awọn eeyan Ọba Momoh lo waa tọ awọn.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ni wahala ta a n wi ọhun ti bẹrẹ wẹrẹ, ti wọn si fa a titi dọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii. O ṣee ṣe ki wọn ṣi maa tẹsiwaju ninu rẹ ti ijọba ko ba tete kede ofin konilegbele oni wakati mẹrinlelogun lọjọ Isẹgun, Tusidee.

Iwadii ALAROYE lori iṣẹlẹ ọhun fi han pe, ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, lawọn eeyan ilu Ikarẹ Akoko, labẹ iṣakoso Olukarẹ, Ọba Saliu Akadri Momoh, pinnu lati ṣe ayẹyẹ orikadun ọjọ Ikarẹ (Ikarẹ day).

Gẹgẹ bii iṣe wọn lọdọọdun, Olukarẹ ni wọn lo paṣẹ pe ko gbọdọ sí tita tabi rira ni gbogbo ọja to wa niluu Ikarẹ lasiko ti wọn ba n ṣe ajọyọ naa.

Bi awọn to wa labẹ iṣakoso Olukarẹ ṣe n kede titi awọn ọja pa lawọn eeyan agbegbe kan ti wọn n pe ni Iyọmẹta yari, ti wọn si ni Ọba Momoh ko laṣẹ rara ko waa ti ọja Osele, eyi to wa nitosi Okoja, pa, nitori pe agbegbe naa ko si labẹ iṣakoso rẹ.

Ọkan ninu awọn alatilẹyin Olukarẹ to ba wa sọrọ ni, ọdọ awọn eeyan Ọkọrun ni rogbodiyan naa ti  bẹrẹ, nitori pe awọn gan-an ni wọn kọkọ lọọ ṣe akọlu sawọn olugbe agbegbe Ọkọja.

Ọkunrin ta a forukọ bo lasiiri ọhun tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe ibi tawọn ti n gbaradi lọwọ fun ayẹyẹ orikadun awọn ni awọn ti gbọ pe awọn ara Ikọrun ti ko ada atawọn nnkan ija lọọ ka awọn eeyan Ọkọja mọle, ti wọn si ti n ṣe wọn leṣe.

O ni ọpọ awọn eeyan ni wọn fara pa ninu akọlu ọhun, eyi to bẹrẹ lati ọjọ Abamẹta, Satide, titi dọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii. Gbogbo awọn ti wọn fara gbọta lo ni awọn gbiyanju ati ko lọ si ileewosan ijọba to wa n’Ikarẹ fun itọju.

Igba ti wọn ṣakiyesi pe awọn eeyan Ọwa Ale tun ti n pete akọlu mi-in lo ni awọn sare lọọ ba awọn ọlọpaa ki wọn le tete wa nnkan ṣe si i, ṣugbọn to jẹ pe bi ilẹ ọjọ Aje, Mọnde, ṣe n mọ lawọn tun ti n gbọ iro ibọn leralera.

Lẹyin ti ẹni akọkọ ti ba wa sọrọ tan, a tun gbiyanju lati wa ẹlomi-in to jẹ eeyan Ọwa Ale ni awari ka le tubọ fidi ododo iṣẹlẹ ọhun mulẹ.

Alaye ti ọkunrin ta a ba sọrọ naa ṣe fun wa ni pe titi ti Olukarẹ fẹẹ fipa ti oja Osẹlẹ pa nitori ayẹyẹ ti wọn fẹẹ ṣe lo da rukerudo silẹ.

O ni awọn eeyan gbiyanju lati daabobo ara wọn nigba ti awọn janduku kan deedee ya wọ inu ọja pẹlu ọpọlọpọ ẹgba lọwọ, ti wọn si n lu awọn ontaja nilukilu nibi ti wọn ti n taja.

Laipẹ lo ni awọn tun ri awọn tọọgi ọhun ti wọn pada lọọ ko ara wọn jọ, ṣugbọn ti awọn naa koju wọn.

Nigba tọrọ naa fẹẹ maa lagbara ju bo ṣe yẹ lọ nijọba ipinlẹ Ondo nipasẹ Kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ, Donald Ọjọgo, sare fi atẹjade kan sita pe Gomina Rotimi Akeredolu ti kede ofin konilegbele oni wakati mẹrinlelogun lẹyẹ-o-ṣọka.

Lati igba naa lawọn agbofinro ti n lọ soke lọ sodo niluu Ikarẹ ati agbegbe rẹ nitori awọn ti wọn le fẹẹ tẹ ofin yii loju.

Gbogbo awọn agbegbe bii aafin Olukarẹ ati ti Ọwa Ale, Ọja Ọba, Iyana Ọlọkọ, Okela, nibi ti wahala naa ti lagbara ju lọ lawọn agbofinro ọhun duro si wamuwamu.

Ko sẹni to to bẹẹ lati patẹ tabi ko ṣi ṣọọbu, koda, lile ni wọn n le awọn ọmọ ileewe pada lọna, ti wọn ko fun wọn laaye lati kọja lọ sibi ẹkọ wọn.

Iroyin to tẹ wa lọwọ lati ilu Ikarẹ lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni pe niwọn igba tawọn eeyan ko ti ri ohunkohun ra mọ laarin igboro Ikarẹ, ilu Arigi ati Ugbe Akoko, ni wọn n lọ bayii lati ra ounjẹ nitori ebi ọgaja fọwọ mẹkẹ.

Leave a Reply