Nitori bi wọn ṣe pa Sọliu, awọn araalu sun mọto kọsitọọmu mẹta l’Ayetoro

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ko din ni mọto awọn kọsitọọmu mẹta tawọn eeyan fibinu danu sun lọjọ Ẹti to kọja yii, l’Ayetoro, nipinlẹ Ogun, nigba tawọn aṣọbode bẹrẹ si i yinbọn leralera, to si ba ẹnikan ti wọn pe orukọ ẹ ni Sọliu. Iṣẹlẹ naa si ti dohun tawọn ọga aṣọbọde bẹrẹ iwadii gidi lori ẹ bayii.
Ohun ti awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ ni pe ẹnikan to jẹ onifayawọ loun ati aṣọbode kan jọ ni gbolohun asọ lọjọ naa laduugbo Oke-Rori, l’Ayetoro. Wọn ni wọn fa ọrọ naa debi kan, awọn eeyan si ba wọn da si i, wọn yanju ẹ, kaluku si ba tiẹ lọ.
Afi bo ṣe di nnkan bii wakati kan lẹyin igba naa ti ọkọ awọn kọsitọọmu mẹrin ya de, n ni wọn ba bẹrẹ si i yinbọn lakọlakọ laarin ilu. Koda, ibọn naa lagbara debii pe wọn ni bii igba ti wọn ti pinnu lati pa gbogbo Ayetoro run ni.
Ọkan ninu awọn gende to ṣalaye iṣẹlẹ naa sọ pe bi ko ba jẹ pe ọpọlọpọ awọn ti ni ajẹsara ni, Ọlọrun nikan lo mọ iye oku ti ko ba sun lọjọ naa. Pẹlu ẹ naa ṣa, ibọn ṣi ba ọmọkunrin kan ti wọn n pe ni Sọliu, wọn ni ẹẹmẹta ni wọn yinbọn mọ ọn ko too wọle si i lara.
Ohun ti awọn aṣọbode naa ṣe yii lo bi awọn araalu ninu, lawọn naa ba doju ija kọ wọn, wọn si dana sun mẹta ninu ọkọ akero Hilux mẹrin ti wọn gbe wa, ko too di pe awọn aṣọbode naa fẹyin rin lọ.
Ṣugbọn Alukoro awọn Kọsitọọmu nipinlẹ Ogun, ẹkun kin-in-ni, Ọgbẹni Hammed Oloyede, sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ lori iṣẹlẹ yii.
O lawọn yoo tuṣu desalẹ ikoko lori ẹ, awọn yoo si fidi ododo mulẹ laipẹ.

Leave a Reply