Nitori bi wọn ṣe tun pa eeyan meji, awọn ọdọ Ayetẹ lawọn o fẹẹ ri Fulani kankan mọ lagbegbe naa

Faith Adebọla

Iwọde nla kan la gbọ pe o n lọ lọwọ lasiko yii ni ilu Ayetẹ, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, lagbegbe Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ. Awọn ọdọ ilu naa atawọn ẹlẹgbẹ wọn lati ilu Tapa ni wọn fẹhonu han latari bawọn Fulani darandaran ṣe ṣeku pa eeyan meji lagbegbe ọhun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii.

Ẹni kan tiṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ, ṣugbọn ti ko fẹ ka darukọ oun, ba ALAROYE sọrọ lori aago pe awọn Fulani darandaran ṣeku pa ọkunrin agbẹ kan niluu Ayetẹ lọjọ Tusidee ọsẹ yii, wọn ni oloogbe ni koun lọọ wo pakute (waya) to dẹ si oko rẹ lo fi pade awọn Fulani darandaran ọhun, bo si ṣe ri wọn lọọọkan lo yi pada, to fere ge e, ṣugbọn wọn ni ilẹ yọ ọ, ibi to ṣubu si lawọn Fulani apaayan naa ṣa a pa si.

Bakan naa ni irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ti waye lọjọ Mọnde to ṣaaju, ti wọn lawọn Fulani darandaran naa pa ẹnikan lati ilu Tapa si ọna oko rẹ.

Ibinu awọn iṣẹlẹ wọnyi la gbọ pe o mu kawọn ọdọ naa kora jọ lowurọ Ọjọbọ, Tọsidee yii, lati ṣewọde lọ saafin ọba ilu Ayetẹ, Ọba Emmanuel Okeniyi, ki wọn si fabọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu ọhun. Koko iwọde wọn ni pe awọn o nigbẹkẹle ninu ijọba mọ pẹlu ọwọ yọbọkẹ ti wọn fi n mu iwa ọdaran ati ipakupa tawọn Fulani darandaran n pa wọn lagbegbe ọhun, ati pe awọn o fẹẹ ri Fulani kan mọ ni gbogbo igberiko ati ilu awọn mọ.

A gbọ pe bi wọn ṣe n kora jọ lọwọ lawọn obinrin kan ninu ilu naa sare waa ta wọn lolobo pe mọto Jiipu Ford Explorer kan ti n bọ lọna, wọn lawọn Fulani ni wọn wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ dudu ọhun.

Ẹnu eyi ni wọn wa ti ọkọ naa fi kan wọn lara, ṣugbọn wọn ni bi awakọ Jiipu naa ṣe ri awọn ọdọ rẹpẹtẹ yii lo duro, o fi ọkọ naa si rifaasi, o fẹẹ fẹyin rin sa lọ, lawọn ọdọ naa ba fipa da a duro, wọn lawọn fẹẹ yẹ ọkọ naa wo.

Wọn ni awọn Fulani mẹta lo wa ninu ọkọ ọhun, wọn si ba ibọn AK-47 kan lọwọ wọn, pẹlu ọta ibọn rẹpẹtẹ ati awọn oogun abẹnu gọngọ. Eyi lo mu kinu tubọ bi awọn ọdọ naa, ni wọn ba yari kanlẹ, wọn lu awakọ Jiipu ọhun lalubami, bo tilẹ jẹ pe awọn Fulani mẹta ti wọn wa ninu ọkọ ọhun sa lọ mọ wọn lọwọ.

Wọn ni ibi tawọn ọdọ naa ti fẹẹ sọ ina si Jiipu naa ni ọga ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ kan ti ko saarin wọn, to si n parọwa pe ki wọn ma ṣe bẹẹ, ṣugbọn alubami ni wọn fi da ọlọpaa ọhun lohun, bẹẹ ni wọn n ṣepe fawọn agbofinro pe awọn ni wọn n gbabọde ti ikọlu awọn Fulani fi de ibi to de yii. Ẹyin eyi ni wọn dana sun ọkọ ọhun, o jona gburugburu. Wọn ni bi jiipu naa ṣe n jona ni iro ọta ibọn to wa ninu ọkọ naa n dun leralera.

Ko pẹ sasiko naa ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Abilekọ Ngozi Ọnadeko, de siluu Ayete fun ipade lori ọrọ aabo ti wọn ti ṣeto tẹlẹ, o si ba wọn lẹnu lọgbọlọgbọ ọrọ ọhun.

Wọn ni kọmiṣanna parọwa fawọn ọdọ naa pe ki wọn fọwọ wọnu, bo tilẹ jẹ pe awọn ọdọ naa lawọn o le ni suuru mọ, niṣe ni ko lọọ ba awọn sọ fun Gomina Ṣeyi Makinde pe awọn o fẹẹ ri Fulani darandaran kan mọ lagbegbe ilu awọn, afi eyi to ba fẹẹ fiku ṣefa jẹ, wọn lohun to ba gba lawọn maa fun un.

Titi di ba a ṣe n sọ yii, funra awọn ọdọ naa ni wọn n da gbogbo ọkọ to ba fẹẹ gba aarin ilu naa kọja, ti wọn si n ṣayẹwo boya Fulani tabi awọn nnkan ija oloro wa wa ninu mọto awọn naa.

Leave a Reply