Nitori biliọnu marundinlogoji Naira to fẹẹ ya, ẹgbẹ kan wọ gomina Kwara lọ sile-ẹjọ 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Fẹsun pe o fẹẹ ya owo kan ti ko din ni biliọnu marundinlogoji naira, ẹgbẹ kan ti orukọ wọn n jẹ Kwara Consultative Stakeholders Forum, ti wọ Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, lọ siwaju ile-ẹjọ giga kan niluu Abuja pe ko da a lọwọ kọ lati ma ya owo naa.

Nọmba iwe ipẹjọ ọhun ni FHC/ABJ/CS/848/2021, leyii ti wọn fi pe Gomina Abdulrahman Abdulrazaq, ile aṣofin  Kwara, Agbẹjọro agba ni Kwara, ileeṣẹ to n ri si idokoowo ni ilẹ yii, ajọ to n ri si paṣipaarọ owo (Securities and Exchange Commission), ileeṣẹ Greenland & Growth SPV Limited, GTL Trustees Limited ati EAC Trustees lẹjọ, ti wọn si sọ pe iye owo ti wọn o maa yọ ati bi owo naa yoo ṣe di sisan pada ni gomina ti buwọ lu, ti yoo si bẹrẹ ni ipari osu yii.

Lati inu oṣu kin-in-ni, ọdun yii ti ile aṣofin ipinlẹ Kwara ti buwọ lu owo yiya ọhun, ni awuyewuye ti n waye, tori pe ẹgbẹ oṣelu alatako nipinlẹ Kwara, PDP, ta ko gomina lori owo to fẹẹ ya naa, bakan naa ni wọn bu ẹnu atẹ lu ile aṣofin Kwara pe gbogbo ohun ti Gomina ba gbe siwaju wọn ni wọn maa n buwọ lu lai ro igbẹyin ọrọ.

 

Leave a Reply