Nitori ẹsun jibiti ori ẹrọ ayelujara, adajọ sọ akẹkọọ Fasiti Ilọrin, KWASU ati Kwara Poly sẹwọn n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Adajọ  Mahmood Abdulgafar tile-ẹjọ giga kan ni Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti sọ  Abubakar Abdulbashir Ọpẹyẹmi, akẹkọọ Fasiti Ilọrin ati awọn akẹkọọ meji miiran,  Alimi Abiodun, akẹkọọ KWASU, ati Idowu Rasaq Olarewaju, akẹkọọ Kwara Poly  sẹwọn n’Ilọrin, fẹsun pe wọn n lu jibiti ori ẹrọ ayelujara tawọn eeyan mọ si ‘Yahoo’.

Ajọ EFCC lo wọ awọn afurasi mẹtẹẹta lọ siwaju Onidaajọ Abdulgafar, fẹsun pe wọn lu awọn eeyan ni jibiti ifẹ lori ẹrọ ayelujara, awọn olujẹjọ mẹtẹẹta si gba pe loootọ lawọn jẹbi ẹsun ti EFCC fi kan wọn.

Nigba ti adajọ Abdulgafar n gbe idajọ rẹ kalẹ, o ni lẹyin ti oun ti ṣe ayẹwo finnifinni lori awọn ẹri ti ajọ EFCC ko siwaju ile-ẹjọ, ti awọn olujẹjọ naa ti gba pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, o ni ki Abdulbashir Ọpẹyẹmi lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa, eyi ti yoo lọọ ṣe lẹyin ọdun kan to ba pari eto ẹkọ rẹ, ki iPhone ati Hp laptop to n lo fun iṣẹ aburu naa di ti ijọba apapọ, to fi mọ ẹgbẹrun lọna aadọta naira ti wọn ba lọwọ rẹ.

Ni ti Abiodun, adajọ ni ko lọọ sẹwọn ọdun kan ati oṣu mẹta, lẹyin ọdun kan to ba pari eto ẹkọ rẹ, ki iPhone to n lo ati ẹgbẹrun lọna ọọdunrun le mejilelaadọta naira (#352,000) ti wọn ba lọwọ rẹ di ti ijọba apapọ.

Adajọ ni ki Rasaq Olanrewaju naa lọọ sẹwọn oṣu mẹfa, ti oun naa yoo si sẹwọn ọhun lẹyin oṣu mẹfa to ba pari eto ẹkọ rẹ, ki ọkọ ayọkẹlẹ Vẹnza rẹ, iPhone to n lo, Hp laptop to n lo, to fi mọ irinwo miliọnu naira le diẹ ti wọn ba ni asunwọn First Banki rẹ ko tijọba apapọ.

 

Leave a Reply