Nitori foonu, Aisha binu da bẹntiroolu sọmọ ẹ lara, lo ba dana sun un ni Mowe

Gbenga Amos, Abẹokuta

 Oriṣiiriṣii epe ati eebu lawọn eeyan n rọjo sori ọdaju abiyamọ kan ti wọn porukọ ẹ ni Aisha Tijani, latari bi wọn ṣe fẹsun kan an pe o fibinu dana sun ọmọ bibi inu ẹ, niṣe lo da bẹntiroolu sọmọ ọdun mẹwaa pere naa lara, o si dana sun un.

Ilu Mowe, nijọba ibilẹ Ọdẹda, nipinlẹ Ogun, niṣẹlẹ naa ti waye logunjọ oṣu Kẹta yii, ọjọ naa lawọn ọlọpaa si ti mu un satimọle wọn.

 Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ṣalaye pe ọkunrin kan tọrọ naa ṣoju ẹ, Ọgbẹni Moroof Ayinde, lo lọọ fẹjọ afurasi ọdaran yii sun ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Mowe, ẹsẹkẹsẹ ni CSP Fọlaṣade Talaruno atawọn ọmọọṣẹ tẹle e lọ sibẹ, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe Aisha.

Abimbọla ni alaye tobinrin naa ṣe ni teṣan ni pe ọmọ marun-un loun bi, foonu ti ọkan ninu wọn n lo loun gba lọwọ rẹ lati fiya jẹ ẹ, oun si tọju foonu naa sibi kan ninu yara wọn, ṣugbọn niṣe lọmọ ọdun mẹwaa yii lọọ mu foonu naa jade nibi toun tọju ẹ si, o si mu un pada fun ẹni toun gba foonu naa lọwọ ẹ, eyi lo bi oun ninu.

Wọn l’ọdaju abiyamọ yii sọ pe oun o tiẹ le ṣalaye nnkan to kọ lu oun toun fi fibinu da bẹntiroolu sara ọmọ oun, toun si ṣana si i lara.

Ninu iwadii tawọn ọlọpaa ṣe, Aisha ni oun ko si nile ọkọ mọ, oun ati baba awọn ọmọ naa ti pinya, oun loun n tọ awọn ọmọ maraarun.

Ṣa, ọsibitu ẹkọ iṣẹgun ti Ọlabisi Ọnabanjọ to wa ni Ṣagamu, lọmọ to dana si lara naa wa bayii, ibẹ ni wọn ti n fun un nitọju akanṣe, tori awọn ọsibitu to wa laduugbo iṣẹlẹ naa ko gba ọmọ ọhun fun itọju.

CP Lanre Bankọle ti paṣẹ fawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lati tubọ wadii iṣẹlẹ yii, ki wọn too taari ẹ siwaju adajọ.

CAPTION

Leave a Reply