Nitori gbeṣe to pọ lọrun ẹ, Ọlakunle para ẹ ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gende-kunrin kan, Ọlakunle Ọbaoye, ẹni ọdun mẹẹẹdogbọn, ti ṣẹku para ẹ nitori gbeṣe to jẹ ni abule kan ti wọn n pe ni Ẹrinmọpe, lẹbaa Ayedun, nijọba ibilẹ Oke-Ẹrọ, nipinlẹ Kwara.

Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, fi sita niluu Ilọrin, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, lo ti salaye pe gende-kunrin ọhun lọ sinu igbo lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, to si lọọ pokunso latari pe gbeṣe ti pọ lọrun ẹ, ti ko si sọna lati san owo naa pada. Lo ba wo o pe iku ya ju ẹsin lọ, o si ṣeku pa ara rẹ.

Ọkunrin naa ni pẹlu iranlọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn fi tu oku ọkunrin naa kuro lara igi, ti wọn si ti gbe e fun awọn mọlẹbi ki wọn le sin oku ọhun.

Wọn ti gbe iṣẹlẹ naa le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ fun ẹkunrẹrẹ iwadii, lẹyin iwadii ni wọn yoo gbe igbesẹ to ba tọ.

Leave a Reply