Nitori ija ilu Ẹrinle ati Ọffa, gomina Kwara kede konilegbele

Stephen Ajagbe, Ilorin
Nitori ija mi-in to tun bẹ silẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, laarin awọn eeyan ilu Ẹrinle, nijọba ibilẹ Ọyun, ati Ọffa, nijọba ibilẹ Ọffa, nipinlẹ Kwara, Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ti kede ofin konilegbele lawọn ilu mejeeji.
ALAROYE gbọ pe aala ilẹ to ti n fa wahala lati ọdun pipẹ lo tun ṣu yọ laarin ilu mejeeji.
Ofin konilegbele ọhun yoo waye lojoojumọ, bẹrẹ lati aago mẹfa irọlẹ si aago mẹjọ aarọ, yoo si tẹsiwaju bẹẹ titi tijọba yoo fi yi i pada.
Atẹjade kan lati ọdọ Akọwe iroyin lọfiisi gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, ni ijọba ti da awọn agbofinro sita lati ri i pe ofin konilegbele naa fidi mulẹ.
Yatọ si awọn ọlọpaa, awọn sọja lati baraaki Sobi pẹlu ọlọpaa adigboluja ti kun gbogbo igboro ilu mejeeji lati ri i pe alaafia wa laarin wọn.
Ijọba ti waa paṣẹ fun gbogbo araalu lati fidi mọle wọn, ko si gbọdọ si ẹnikẹni lawọn agbegbe ti wọn n ja le lori.
Gbogbo awọn arinrin-ajo to n gba ọna naa kọja gbọdọ tẹle ofin konilegbele naa lọna ati daabo bo ẹmi ati dukia araalu.
Bakan naa nijọba gba awọn adari ilu mejeeji niyanju lati pẹtu sawọn eeyan wọn ninu,

Leave a Reply