Nitori iwọde ‘Orileede Odua’ tawọn kan fẹẹ ṣe ni Satide, Odumosu da ọpọlọpọ ọlọpaa sita l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Hakeem Odumosu, tun ti jade laago ikilọ pe kẹnikẹni ma ṣe da a laṣa pe awọn fẹẹ ṣe iwọde idasilẹ ‘Orileede Oodua’, tabi iwọde eyikeyii lọla, tori ida ofin maa ge onitọhun lai ka iru ẹni yoowu ko jẹ si ni.

Lọjọ Ẹti, Furaidee yii, ni gbagede ọgba olu-ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Eko, eyi to wa n’Ikẹja, nibi to bi n ba awọn ikọ ọlọpaa ti wọn ti dihamọra ija, eyi ti wọn fẹẹ da sigboro lati koju iwọde eyikeyii to le fẹẹ waye, ni Odumosu ti sọrọ ọhun.

Kọmiṣanna ni gbogbo ọna to bofin mu lawọn yoo tọ lati gbegi dina iwọde yoowu to le fẹẹ waye ọhun, ibaa jẹ iwọde alalaafia tabi ti ifẹhonu han.

Pẹlu bi nnkan ṣe ri yii, ẹru ti n ba ọpọ awọn araalu latari bi ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho ṣe kede lowurọ ọjọ Ẹti, Furaidee yii kan naa pe ko sohun to maa da awọn duro lẹnu iwọde ‘Oodua Nation’ tawọn gun le, o ni iwọde naa maa waye bo ṣe yẹ ko waye lọjọ Satide, Abamẹta yii, bẹrẹ lati aago mẹsan-an owurọ.

O ni agbegbe Ọjọta ni ojuko iwọde ọhun, bo tilẹ jẹ pe kaakiri awọn agbegbe ilu Eko lawọn ti fẹẹ ṣe e, tori aṣekagba iwọde nla ni, eyi tawọn eleebo n pe ni Mega Rally.

Ṣaaju nileeṣẹ ọlọpaa Eko ti kọkọ kede ninu atẹjade kan l’Ọjọbọ, Tọsidee, pe awọn ko ni i faaye gba iwọde kankan niluu Eko, tori awọn ti gbọ finrinfinrin pe awọn janduku kan fẹẹ fi iwọde ọhun boju lati ṣiṣẹẹbi.

Bẹẹ la gbọ pe Sunday Igboho ti kọkọ wọgi le iwọde ọhun, latari bawọn ṣọja atawọn ẹṣọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ijọba apapọ ilẹ wa, DSS, ṣe lọọ ṣakọlu sile ajijagbara naa to wa lagbegbe Sọka, Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, wọn paayan meji, wọn ko awọn bii mọkanla, wọn lawọn ba awọn ohun ija oloro bii ibọn, oogun abẹnu gọngọ atawọn dukia mi-in, gbogbo ẹ ni wọn ti ko lọ s’Abuja.

Bakan naa ni wọn kede pe awọn n wa Oloye Sunday Igboho, wọn ni ko funra ẹ yọju sawọn tabi kawọn mu un nibikibi ti wọn ba ti pade ẹ.

Leave a Reply