Nitori iwọde SARS, INEC sun idibo Eko atawọn mi-in siwaju

Aderounmu Kazeem

Ajọ eleto idibo Naijria, INEC ti kede wi pe gbogbo awọn idibo kan to yẹ ko waye laipẹ yii lawọn ti sun siwaju bayii.

Ipari oṣu yii, iyẹn ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹwaa yii, lo yẹ ki eto idibo sile igbimọ aṣofin agba ati ile igbimọ aṣofin Eko waye, lati fi rọpo awọn oloṣelu meji kan ti wọn salaiṣi laipe yii.

Ohun ti ajọ INEC sọ ni pe, pẹlu gbogbo wahala to n ṣẹlẹ yii, ko ni i bojumu ti oun ba tẹ siwaju pẹlu eto idibo ọhun.

Eto idibo yii yẹ ko waye lawọn ipinlẹ mọkanla kaakiri Naijiria.

Leave a Reply