Nitori ki wọn ma baa sanwo ti wọn jẹ ẹ, awọn eleyii pa ọrẹ wọn, wọn ju oku ẹ si kanga

Awọn ọkunrin meji yii ti wa lọdọ awọn ọlọpaa nipinlẹ Kaduna bayii, wọn n ṣalaye lori iku ti wọn fi pa ọrẹ wọn, Idris Bashir, ẹni ti wọn jẹ lẹgbẹrun lọna irinwo din diẹ naira(385,000) ti wọn si tan an lọ sile akọku, ti wọn pa a, ti wọn sọ oku ẹ si kanga lọjọ kẹrin, oṣu kẹfa, ọdun 2021 yii.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kaduna ti iṣẹlẹ yii ti waye, ASP Mohammed Jalige, ṣalaye pe Baba Idris ti wọn pa lo waa fọrọ naa to ọlọpaa leti, pe ọmọ oun jade nile lati ọjọ kẹrin, oṣu kẹfa, ko si pada wale mọ.

O ni Baba Idris sọ pe ọrẹ ọmọ oun torukọ ẹ n jẹ Mannir Salihu, loun fura si nipa aiwale ọmọ naa.

Bayii lawọn ọlọpaa bẹrẹ itọpinpin, wọn ri Mannir mu, lo ba ni ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ, oun nikan kọ loun huwa naa, oun ati ọrẹ awọn kẹta torukọ tiẹ n jẹ  Aliyu Yahaha ni. Aliyu Yahaya to n gbe l’Ojule kẹrindinlọgọrun-un, Anguwan Magajiya, ni Zaria.

O lawọn mejeeji lawọn jọ tan Idris wọ ile akọku, nibi tawọn pa a si, tawọn si ju oku ẹ sinu kanga kan tawọn eeyan ko lo mọ.

Nigba ti wọn n ṣalaye idi ti wọn fi pa ọrẹ wọn naa, awọn mejeeji yii sọ pe Idris ya awọn lowo to din diẹ ni irinwo naira, awọn ko si fẹẹ sanwo naa pada fun un mọ, nitori ẹ lawọn ṣe pa a danu, oku ko kuku ni i waa beere owo lọwọ awọn.

Wọn pada mu awọn ọlọpaa lọ sibi kanga ti wọn ju ọrẹ wọn naa si, awọn ọlọpaa si hu u, wọn gbe e lọ sọsibitu  Jẹnẹra Hajiya Gambo Sawaba, fun ayẹwo, wọn si yọnda oku naa fawọn ẹbi ẹ lati lọọ sin in nilana ẹsin Islam.

Leave a Reply