Nitori ọgọrun-un kan naira, ṣọja yinbọn lu awọn awakọ ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

O kere ju eeyan marun-un lo fara gba ọta lọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ to kọja yii, nigba tawọn ọmọ ogun atawọn awakọ kọju ija sira wọn nitori ọgọrun-un kan naira niluu Ileṣha-Baruba, nijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe ohun to da wahala naa silẹ ni bawọn awakọ ero ṣe kọ lati san ọgọrun-un kan naira fawọn sọja to maa n wa loju ọna Ileṣha-Baruba si Ṣinawu, ko too di pe wọn raaye kọja.

Ọkan lara awọn dẹrẹba tawọn sọja da duro ta ku jalẹ pe oun ko le san owo mi-in nitori pe oun ti san ọgọrun-un naira tẹlẹ lasiko toun n lọ si ọja Ṣinawu.

Nigba ti wọn ni ariyanjiyan n waye ni ọkan lara awọn sọja gba eti awakọ ọhun, kia niyẹn lọọ pe awọn ẹlẹgbẹ rẹ ni gareeji lati waa gbeja rẹ.

Akọroyin wa gbọ pe bi wọn ṣe ko ara wọn debẹ lawọn sọja koju ibọn si wọn, n lọrọ ba dija igboro, o di ẹni ori yọ o dile.

Ọkan lara awọn to maa n na ọja naa daadaa ṣalaye pe ọjọ Ẹti tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ gan-an ni ọjọ ọja yii, kaakiri awọn ilu to wa nitosi ijọba ibilẹ Baruten, titi de ilu Ọyọ, lawọn eeyan ti maa n wa naja Ṣinawu.

O ni bawọn sọja ṣe maa n gba owo lọwọ awọn awakọ niyẹn. Bẹrẹ lati ọgọrun-un kan naira titi de ọgọrun-un marun-un ni wọn maa n gba lọwọ dẹrẹba. Bi mọto ti onitọhun ba wa ṣe tobi si ati bi ẹru to ba ko ṣe pọ si ni wọn fi maa n sọ iye tawọn maa gba.

Leave a Reply