Jọkẹ Amọri
Gbogbo awọn ti wọn ri oṣere ilẹ wa to ṣẹṣẹ bi ibeji laipẹ yii to n sunkun gidigidi ni wọn n ba a kaaanu, ọpọ ni ko si mọ pe ẹkun ayọ ni oṣere naa n sun.
Ṣeyi Edun, oṣere toun naa fẹ oṣere ẹgbẹ rẹ lo n sunkun ninu fidio kan to jade laipẹ yii. Lọjọ ti wọn n ṣe isọmọlorukọ awọn ibeji to ṣẹṣẹ bi lo n bomi loju kikan kikan.
Awọn to ba mọ iriri ti ọmọbinrin naa ti la kọja nikan lo maa mọ idi ti oṣere yii fi n sunkun. Lati bii ọdun meje sẹyin lo ti fẹ ọkọ rẹ, Adeniyi Johnson, to ti figba kan jẹ ọkọ Toyin Abraham toun naa ti pada fẹ oṣere ẹgbẹ rẹ mi-in, Kọlawọle Ajeyẹmi.
Ọpọ ẹlẹya ni awọn eeyan fi ọṣere yii ṣe lasiko to fi n woju Ọlọrun fun ọmọ yii. Bawọn kan ṣe n pe e ni akọ ibẹpẹ lawọn mi-in n fi oriṣiiriṣii orukọ pe e.
Eyi to buru ju ti oṣere naa sọ, to si ni oun ko le gbagbe laelae ni ti ẹnikan ti ko mọ ri, to si kọ ọrọ ranṣẹ si i lori Instagraamu rẹ pe ko mọ ju ko maa jo ijo ẹlẹya, ko si maa jẹun lọ. O ni Ṣeyi Ẹdun to ti di Iya Ibeji bayii ko ye, ko pa, eyi ko si jẹ itiju fun un, dipo ko ronu lori eleyii, niṣe lo n jo ijokijo kiri ori ẹrọ ayelujara, to si n gbe fidio ounjẹ oriṣiiriṣii han faye ri. O ni kaka ko ronu lori ipo agan to wa, ounjẹ lo fi n jẹ.
Ṣugbọn ẹni to n bu oṣere yii ko mọ ni gbogbo igba naa pe Ṣeyi ti diwọ disẹ sinu, o ti n reti awọn ibeji lọna.
Eyi ni bi ẹni naa ṣe kọ ọrọ eebu to kọ si oṣere yii.
‘‘Anti agan, ṣọra ki o ma fori gbe epe elepe
Olounjẹ oṣi, Misisi agan, alainironu
O ko mọ ju ki o maa jẹ ṣinkin ati iwe adiyẹ lọ.
‘‘Lọọ bimọ ka ri i, o kọ, o ko bimọ, o si tun n gbe awọn kan ṣepe
Eyi to fi yẹ ki o din ara sisan rẹ ku, ki o si maa sunkun si ẹlẹdaa rẹ lọrun. Oponu, o kan n sanra ṣaa lai si ọmọ kankan to o bi.
Ko o jẹun, ko o sun, ko o ji nikan lo mọ. Iya to bi ọ paapaa kan jokoo, ko ṣe ohunkohun lori ọrọ rẹ. Ori Toyin lo mu ẹ ṣa, agan naa ni wa a si ya ku. Wa ọna abayọ si iyagan rẹ, ki o yee jo ijo ẹlẹya kiri ori ayelujara.
‘‘Gbogbo awọn ẹgbẹ rẹ ni wọn n ki ku ewu ọmọ, nigba wo ni wọn maa ki iwọ naa ku oriire, Arabinrin Agan. Ọdun yii ti tun kọja o, alainironu ara Galatia’’.
Ṣeyi ni ninu oṣu Kẹwaa, ọdun to kọja, ni ẹni ti oun ko mọ ri yii kọ ọrọ naa ranṣẹ soun, ṣugbọn oun ti wa ninu oyun awọn ibeji yii nigba naa.
Awọn nnkan wọnyi lo jọ pe Seyi ranti bo ṣe gbe awọn ibeji rẹ lọwọ, to n wo wọn pe ṣe oun naa le di ọlọmọ laye, ti omi ẹkun si n jade loju rẹ. Ṣugbọn ki i ṣe omi ẹkun kikoro, ẹkun ayọ ni oṣere naa n sun. Gbogbo awọn ti wọn sun mọ ọn ni wọn n rẹ ẹ lẹkun, ti wọn si n sọ fun un pe ọrọ rẹ ti dayọ, ayọ naa lo ku ko maa yọ, nitori Ọlọrun ti ṣọ ẹgan rẹ di ogo.
Ayọmikun Ayọmipọsi ni wọn sọ orukọ aọn ibeji naa.
Gbogbo aye lo si n ba Seyi Ẹdun ati ọkọ rẹ taọn mejeeji jẹ oṣere dupẹ pe ẹgan wọn ti di ogo.