Nitori ominira Yoruba: Wọn nijọba Naijiria ti n kọ lu awọn ẹbi Ọjọgbọn Banji Akintoye

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua (IOO), iyẹn ọkan ninu awọn ẹgbẹ to n pe fun idasilẹ Orilẹ-ede Olominira Yoruba ti kegbajare nipa ẹbi olori ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Banji Akintoye. Wọn ni awọn kan ninu ijọba Naijiria ti bẹrẹ si i kọ lu awọn ẹbi baba naa bayii, nitori ati da a lẹkun lori ijangbara Yoruba to mu ni koko.

Ẹgbẹ yii sọ pe ọkan lara awọn iyawo ọmọ Ọjọgbọn Akintoye, ẹni ti wọn fi orukọ bo laṣiiri, bọ lọwọ awọn to fẹẹ pa a lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, nile rẹ lagbegbe Agbor, nipinlẹ Delta, to n gbe. Wọn fẹẹ pa a ni, ori lo ko o yọ.

Ninu atẹjade kan ti Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua fi sita lati ọwọ Akọwe iroyin wọn, Maxwell Adelẹyẹ, ni wọn ti ṣalaye pe niṣe lawọn kan lọọ sọ ina si ile mọlẹbi Akintoye laarin ọsẹ, ti dukia to to miliọnu lọna aadọrin (70m) si ṣegbe sinu ina. Wọn fi kun un pe odo ẹja onimiliọnu iyebiye ti wọn ṣe sinu ile naa bajẹ pẹlu, nigba ti awọn ẹja nla nla to wa nibẹ ṣegbe sinu ina ọhun.

Wọn tẹsiwaju pe awọn iranṣẹ ijọba to n lepa ẹmi awọn eeyan Akintoye kiri yii tun dọdẹ ọkan ninu awọn ẹbi naa to jẹ ọkan ninu awọn aṣofin ilẹ yii ri, wọn ni wọn ṣaa n wa ọna ti wọn yoo fi ṣi wọn lọwọ nidii ijangbara Yoruba yii. Ṣugbọn ẹgbẹ IOO lawọn ko ni i pada sẹyin, aṣeye lawọn yoo ṣe ti ilẹ Olominira Yoruba yii.

‘‘A n sọ fun gbogbo ọmọ Yoruba nile ati lẹyin odi pe awọn iranṣẹ ijọba Naijiria ti bẹrẹ igbesẹ eṣu lati da olori wa, Ọjọgbọn Banji Akintoye, lẹkun lori ọrọ ijangbara Yoruba, niṣe ni wọn n dọdẹ awọn ẹbi wọn kiri.

‘‘Ọsẹ diẹ sẹyin lo ti bẹrẹ, a o kan sọ ọ sita ko ma baa tun da kun ipaya to ti wa nilẹ tẹlẹ ni, o di dandan fun wa lati sọrọ bayii la ṣe sọ ọ jade.

‘‘Awa ti Ilana Ọmọ Oodua n fi asiko yii sọ fun gbogbo ọmọ Yoruba, pe bi ohunkohun ba ṣẹlẹ si olori wa, Alana, Ọjọgbọn Banji Akintoye, tabi si ẹnikẹni ninu ẹbi rẹ, ijọba Naijiria la maa mu o.

‘‘Nigba tawọn apaayan yii pa ọmọ ọkan lara awọn aṣaaju ilẹ Yoruba, wọn kan foju awọn afurasi rẹ han lasan ni, ko sohun to ṣẹlẹ latigba naa mọ.

‘‘Iroyin aburu ta a ni fawọn iranṣẹ Eṣu yii ni pe ẹru ko ni i ba wa, wọn ko si ni i ko wa laya jẹ. Arọni o wale, Onikoyi o sinmi ogun ni.

Leave a Reply