Nitori ọmọ ilu kan to ku lojiji, awọn ọdọ fẹhonu han, wọn tun le ọba kuro laafin n’Ita-Ogbolu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọgọọrọ awọn ọdọ ni wọn jade niluu Ita-Ogbolu, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lati fẹhonu han ta ko iṣẹlẹ iku ọmọ ilu naa kan, Ayọ Oloyede.

Ọna marosẹ kan ṣoṣo to gba aarin ilu Ita-Ogbolu kọja lọ si ipinlẹ Ekiti lawọn olufẹhonu han naa kọkọ di pa, ti wọn ko si fun awọn arinrin-ajo laaye lati kọja fun bii ọpọ wakati.

Lẹyin eyi ni wọn ṣẹṣẹ mori le aafin, nibi ti wọn ti fagidi le Ọba Idowu Faborede ti i ṣe Ogbolu ti Ita-Ogbolu kuro laafin tipatipa.

Ni ibamu pẹlu ohun ti akọroyin wa fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ọkan lara awọn tinu n bi ọhun, o ni ọmọ bibi ilu awọn ni Oloyede, ati pe ọkan pataki ni i ṣe ninu awọn ti awọn gbẹkẹle pe yoo tun ọjọ ọla ilu naa ṣe nipasẹ iṣẹ ọlọpaa to n ṣe.

O ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, lo sare wa sile lati waa bẹ iya rẹ wo labule kan ti ko fi bẹẹ jinna siluu awọn.

Asiko to n pada siluu Akurẹ, nibi to fi ṣebugbe, lo ku lojiji ninu ijamba ọkọ kan to waye nitosi abule kan ti wọn n pe ni Odudu, to wa laarin Akurẹ si ilu wọn.

Ọkọ ayọkẹlẹ ti Oloyede wọ lo deedee takiti lojiji, lai si idi kan pato, ọkunrin ọhun ni ohun to ya awọn lẹnu ju ni bo ṣe jẹ pe Oloyede to jokoo si ijokoo ẹyin nikan lo ku ninu ijamba ọkọ naa, ti ko si ohun to ṣe awakọ to wa niwaju.

O ni awọn fura si iku ọlọpaa kogbereegbe ọhun pe ki i ṣoju lasan, idi ree ti pupọ awọn ọdọ fi n binu, ti wọn si lọọ fipa le kabiyesi kuro laafin rẹ latari bi ko ṣe bikita nipa iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply