‘Nitori ọrẹbinrin mi to nilo ẹgbẹrun mẹwaa naira ni mo ṣe lọọ ji ọgẹdẹ bẹ loko oloko’

Peres Double lorukọ ọkunrin to jokoo laarin ọgẹdẹ yii, niṣe lo ji awọn ọgẹdẹ ọhun bẹ kaakiri oko oloko ni Bayelsa. Nigba tọwọ si ba a, o ni ọrẹbinrin oun lo nilo ẹgbẹrun mẹwaa naira, nitori ẹ loun ṣe lọọ jale loko ọgẹdẹ

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu karun-un yii, lọwọ ba Peres, laduugbo Ebedebiri, nijọba ibilẹ Sagbama, ni Bayelsa.

O ti bẹ awọn ọgẹdẹ ọhun tan, ko ta a lo ku u ti wahala fi de ba a. Nigba to n ṣalaye idi ẹ to fi jale, ọmọkunrin naa sọ pe ọrẹbinrin oun fẹẹ ra nnkan iṣojuloge (make-up), ẹgbẹrun mẹwaa naira lo si pe e.

O ni ọmọbinrin naa sọ pe boun ko ba rowo naa ko silẹ tọjọ toun da ba fi pe, wahala ni.

O loun ko fẹ wahala ti yoo jẹ kọmọ naa fi oun silẹ, ohun to jẹ koun wọ awọn oko ọgẹdẹ kiri niyẹn toun bẹ wọn lọ pẹlu ireti ati ta a, koun le ri ẹgbẹrun mẹwaa naira tu jọ fun ọrẹbinrin oun.

Ẹbẹ lo bẹrẹ si i bẹ nigba tọwọ ba a, o ni ki wọn dakun, foriji oun, nitori ifẹ loun ṣe ṣiwa-hu.

Leave a Reply