Ọkunrin yii pa ọrẹ ẹ ti wọn jọ n gbe yara, o ta ẹya ara ẹ fun pasitọ

K’Ọlọrun maa ṣọ wa lọwọ ẹni ti a ko ṣọ to n ṣọ ni, agba adura to yẹ keeyan maa ṣe ni. Ohun lọrọ ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn yii, Okpegboro Avwerosuo, ẹni to tan ọrẹ ẹ wa si Bayelsa pe ko waa ṣiṣẹ, ti ko si ti i pe ọsẹ meji ti ọkunrin naa de to fi la ọmọ ori odo mọ ọn lori, to si pa a laarin oru.

Koda, o tun ta ẹya ara ẹ fun pasitọ kan to fẹẹ fi i ṣowo!

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Bayelsa lo mu Okpegboro yii, ti wọn si jẹ ki ohun to ṣe han saye. Ibi kan ti wọn n pe ni Mile 2, niluu Sagbama, nipinlẹ Bayelsa, lo n gbe, ṣugbọn ọmọ Ughelli, nipinlẹ Delta ni.

Okpegboro pe ọrẹ ẹ naa pe ko maa bọ lọdọ oun ni Sagbama, ko kuro niluu awọn ti nnkan ko ti ṣenuure fun un. O ni ko maa waa ṣiṣẹ ọkada ni Sagbama, nitori iṣẹ naa pe nibẹ daadaa, awọn ọmọọleewe giga to wa lagbegbe awọn maa n jẹ ki ọkada gigun ya nibẹ gan-an.

Eyi lọrẹ naa gbọ to fi palẹ ẹru rẹ mọ, to kọri si Bayelsa lọdọ Okpegboro, ko mọ pe o fẹẹ pa oun ni.

Ko ti i to ọsẹ meji ti ọrẹ naa de gẹgẹ bi araale kan ṣe wi, ti Okpegboro fi ran an niṣẹ ti ko fẹẹ jẹ.

Awọn ọlọpaa sọ pe afurasi yii jẹwọ fawọn pe laarin oru loun la ọmọri odo mọ ọrẹ oun lori, to ku patapata.

Wọn lo sọ pe oun yọ awọn ẹya ara rẹ to wulo fun oogun owo ṣiṣe, oun tọju rẹ, oun si ko awọn eyi ti ko wulo da sapo, oun lọọ ju u nu lọwọ idaji.

Ara ile rẹ kan to ri i nigba to n da ẹya ara eeyan nu ninu apo fura si i, iyẹn si ko o loju pe nibo ni ọrẹ rẹ to n gbe lọdọ rẹ wa. Ọrọ ṣaa pada di ti ọlọpaa, bi wọn ṣe waa gbe Okpegboro lọ niyẹn.

O ti jẹwọ fawọn ọlọpaa Bayelsa bi wọn ṣe wi, o si  loun ta ẹya ara ẹ to ṣe pataki fun pasitọ kan to ti sa lọ bayii ni. O ni pasitọ naa fẹẹ fi i ṣoogun owo ni. Oun ti wa lahaamọ ni tiẹ, awọn ọlọpaa n wa ẹni keji rẹ to ta ẹya ara eeyan fun.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

2023: Ẹgbẹ TOTT rọ Tinubu atawọn oludije yooku lati panu pọ gbe Ọṣinbajo kalẹ

Ọrẹoluwa Adedeji Ẹgbẹ kan, The Ọsinbajo Think Tank (TOTT), ti parọwa si aṣaaju ẹgbẹ oṣelu …

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: