Ko nilo ka paarọ iwe ofin ọdun 1999 ti Naijiria n lo bayii-Olurẹmi Tinubu

Faith Adebọla, Eko

Sẹnetọ to n ṣoju Aarin-Gbungbun ilu Eko nileegbimọ aṣofin agba, Olurẹmi Tinubu, ti fi erongba rẹ han lori iwe ofin ilẹ wa tọdun 1999, eyi ti a n lo lọwọ yii, o loun ko fara mọ erongba awọn kan ti wọn n pe fun pipaarọ iwe ofin naa, o niyẹn ko le yanju iṣoro orileede yii.

Tinubu ni ohun to daa ju ni ka ṣatunṣe sawọn ibi to ba yẹ ninu iwe ofin naa, dipo ta a fi maa bẹrẹ kikọ iwe ofin miiran lakọtun.

Olurẹmi sọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaidee yii, nigba to n ṣalaye fawọn oniroyin nipa bi eto apero itagbangba lori ṣiṣatunṣe si iwe ofin ilẹ wa to waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, si Ọjọbọ, Tọsidee, l’Ekoo, ṣe lọ si, ati gẹgẹ bii alaga apero ọhun ni ẹkun Guusu/Iwọ-Oorun.

O ni: “Awọn to n ni ka wọgi le iwe ofin ta a n lo lọwọ yii, wọ o ri i sọ o, iyẹn si kọ lọna abayọ forileede wa. Ta lo sọ pe to ba fi maa di ọdun mẹwaa si mẹẹẹdogun si i, wọn o tun ni i sọ pe ka tun ṣewe ofin mi-in, pe eyi ta a ba ṣe nisinyii ko tun bode mu mọ?

Iyawo agba-ọjẹ oloṣelu ilu Eko nni, Aṣiwaju Bọla Tinubu, sọ pe gbogbo aba ati ero tawọn eeyan sọ ateyi ti wọn kọwe rẹ sọwọ lati Eko, Ogun ati Ọyọ lawọn maa ko jọ, tawọn si maa ṣaṣaro le lori pẹlu awọn aba mi-in lati awọn ibudo apero mẹwaa to ku lorileede yii.

O ni iwe ofin tawọn maa mu jade lẹyin igbokegbodo yii maa tẹ awọn ọmọ Naijiria lọrun, awọn o si ni i figba kan bọ ọkan ninu nigba tawọn aṣofin ba bẹrẹ ijiroro wọn.

Abilekọ ẹni ọgọta ọdun naa ni tawọn ba ti mu abadofin jade lori ẹ, ti Aarẹ Buhari ba si ti buwọ lu u lati sọ ọ dofin, awọn ọmọ orileede yii le fọkan balẹ lati ri igba ọtun ti wọn n beere fun.

Leave a Reply