Ẹni kan ku nibi ija ọlọpaa atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Lowuurọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan bẹ sinu ira, nigba to n gbinyanju lati sa mọ awọn ọlọpaa lọwọ, ni agbegbe Baboko, Ọja Tuntun, Surulere, n’Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji ọtọọtọ ni wọn ṣe akọlu sira wọn, ti wọn si n da omi alaafia agbegbe Ọja Tuntun, Baboko ru. Awọn ọlọpaa lọ sibẹ lati da alaafia pada, wọn si mu mejila ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii, sugbọn ọrọ naa pada da wahala silẹ.

Ọkan ninu awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun ti wọn ko ṣẹkẹṣẹkẹ si lọwọ lo fẹ fẹṣẹ fẹ ẹ, lo ba bẹ sinu ira, eyi lo da ipaya silẹ laarin awọn ọlọpaa, ni wọn ba ke si ajọ panapana. Wọn yọ ọkunrin naa jade loootọ, ṣugbọn oku rẹ ni wọn gbe jade nitori o ti jẹ Ọlọrun nipe.

Eyi lo bi awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ninu ti wọn fi kora wọn jọ, ti wọn si fẹẹ lọ sakọlu si agọ ọlọpaa (B. Division), to wa lagbegbe Surulere, n’Ilọrin. Bayii lawọn at’ọlọpaa bẹrẹ si i dana ibọn yara wọn.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni alaafia ti pada jọba ni agbegbe naa bayii, ati pe awọn yoo ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply